33 Nitori Ọlọrun kì iṣe Ọlọrun ohun rudurudu, ṣugbọn ti alafia, gẹgẹ bi o ti jẹ ninu gbogbo ijọ enia mimọ́.
34 Jẹ ki awọn obinrin nyin dakẹ ninu ijọ: nitori a kò fifun wọn lati sọrọ, ṣugbọn jẹ ki wọn wà labẹ itẹriba, gẹgẹ bi ofin pẹlu ti wi.
35 Bi nwọn ba si fẹ kọ́ ohunkohun, ki nwọn ki o bère lọwọ ọkọ wọn ni ile: nitori ohun itiju ni fun awọn obinrin lati mã sọrọ ninu ijọ.
36 Kini? lọdọ nyin li ọ̀rọ Ọlọrun ti jade ni? tabi ẹnyin nikan li o tọ̀ wá?
37 Bi ẹnikẹni ba ro ara rẹ̀ pe on jẹ woli, tabi on jẹ ẹniti o li ẹmí, jẹ ki nkan wọnyi ti mo kọ si nyin ki o ye e daju pe ofin Oluwa ni nwọn.
38 Ṣugbọn bi ẹnikan ba jẹ òpe, ẹ jẹ ki o jẹ òpe.
39 Nitorina, ará, ẹ mã fi itara ṣafẹri lati sọtẹlẹ ki ẹ má si ṣe danilẹkun lati fi ède fọ̀.