5 Ṣugbọn iba wu mi ki gbogbo nyin le mã sọ oniruru ède, ṣugbọn ki ẹ kuku mã sọtẹlẹ: nitori ẹniti nsọtẹlẹ pọ̀ju ẹniti nsọ oniruru ède lọ, ayaṣebi o ba nṣe itumọ̀, ki ijọ ki o le kọ́ ẹkọ́.
6 Njẹ nisisiyi, ará, bi mo ba wá si arin nyin, ti mo si nsọrọ li ede aimọ̀, ère kili emi o jẹ fun nyin, bikoṣepe mo ba mba nyin sọrọ, yala nipa iṣipaya, tabi nipa imọ̀, tabi nipa isọtẹlẹ, tabi nipa ẹkọ́?
7 Bẹni pẹlu awọn nkan ti kò li ẹmí ti ndún, ibã ṣe fère tabi dùru, bikoṣepe ìyatọ ba wà ninu ohùn wọn, a ó ti ṣe mọ̀ ohun ti fère tabi ti dùru nwi?
8 Nitoripe bi ohùn ipè kò ba daju, tani yio mura fun ogun?
9 Bẹ̃ si li ẹnyin, bikoṣepe ẹnyin ba nfi ahọ́n nyin sọrọ ti o ye ni, a o ti ṣe mọ̀ ohun ti a nwi? nitoripe ẹnyin o sọ̀rọ si ofurufu.
10 O le jẹ pe oniruru ohùn ni mbẹ li aiye, kò si si ọ̀kan ti kò ni itumọ.
11 Njẹ bi emi kò mọ̀ itumọ ohùn na, emi o jasi alaigbede si ẹniti nsọ̀rọ, ẹniti nsọ̀rọ yio si jasi alaigbede si mi.