12 Ti a nṣe lãlã, a nfi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ: nwọn ngàn wa, awa nsure; nwọn nṣe inunibini si wa, awa nforitì i:
13 Nwọn nkẹgàn wa, awa mbẹ̀bẹ: a ṣe wa bi ohun ẹgbin aiye, bi ẽri ohun gbogbo titi di isisiyi.
14 Emi kò kọ̀we nkan wọnyi lati fi dojutì nyin, ṣugbọn lati kìlọ fun nyin bi awọn ọmọ mi ayanfẹ.
15 Nitori bi ẹnyin tilẹ ni ẹgbarun olukọni ninu Kristi, ṣugbọn ẹnyin kò ni baba pipọ: nitoripe ninu Kristi Jesu ni mo ti fi ihinrere bí nyin.
16 Nitorina mo bẹ̀ nyin, ẹ mã ṣe afarawe mi.
17 Nitorina ni mo ṣe rán Timotiu si nyin, ẹniti iṣe ọmọ mi olufẹ ati olododo ninu Oluwa, ẹniti yio ma mu nyin ranti ọ̀na mi ti o wà ninu Kristi, gẹgẹ bi mo ti nkọ́ni ninu gbogbo ijọ nibigbogbo.
18 Ṣugbọn awọn ẹlomiran gberaga ninu nyin, bi ẹnipe emi kì yio tọ̀ nyin wá mọ́.