2 Pẹlupẹlu a mbere lọwọ iriju pe ki oluwarẹ̀ na ki o jẹ olõtọ.
3 Ṣugbọn, ohun kikini ni fun mi pe, ki ẹ mã ṣe idajọ mi, tabi ki a mã ṣe idajọ mi nipa idajọ enia: nitotọ emi kò ṣe idajọ emi tikarami.
4 Nitoriti emi kò mọ̀ ohunkohun si ara mi; ṣugbọn a kò ti ipa eyi dá mi lare: Ṣugbọn ẹniti nṣe idajọ mi li Oluwa.
5 Nitorina, ẹ máṣe ṣe idajọ ohunkohun ṣaju akokò na, titi Oluwa yio fi de, ẹniti yio mu ohun òkunkun ti o farasin wá si imọlẹ, ti yio si fi ìmọ ọkàn hàn: nigbana li olukuluku yio si ni iyìn tirẹ̀ lọdọ Ọlọrun.
6 Njẹ ará, nkan wọnyi ni mo ti fi ṣe apẹrẹ ara mi ati Apollo nitori nyin; ki ẹnyin ki o le ti ipa wa kọ́ ki ẹ maṣe ré ohun ti a ti kọwe rẹ̀ kọja, ki ẹnikan ninu nyin ki o máṣe ti itori ẹnikan gberaga si ẹnikeji.
7 Nitori tali o mu ọ yàtọ? kini iwọ si ní ti iwọ kò ti gbà? njẹ bi iwọ ba si ti gbà a, éhatiṣe ti iwọ fi nhalẹ, bi ẹnipe iwọ kò gbà a?
8 A sá tẹ́ nyin lọrùn nisisiyi, a sá ti sọ nyin di ọlọrọ̀ nisisiyi, ẹnyin ti njọba laisi wa: iba si wu mi ki ẹnyin ki o jọba, ki awa ki o le jùmọ jọba pẹlu nyin.