9 Nitori mo rò pe Ọlọrun ti yan awa Aposteli kẹhin bi awọn ẹniti a dalẹbi ikú: nitoriti a fi wa ṣe iran wò fun aiye, ati fun angẹli, ati fun enia.
10 Awa jẹ aṣiwere nitori Kristi, ṣugbọn ẹnyin jẹ ọlọgbọ́n ninu Kristi; awa jẹ alailera, ṣugbọn ẹnyin jẹ alagbara; ẹnyin jẹ ọlọlá, ṣugbọn awa jẹ ẹni ẹ̀gan.
11 Ani titi fi di wakati yi li ebi npa wa, ti òrungbẹ si ngbẹ wa, ti a si wà ni ìhoho, ti a si nlù wa, ti a kò si ni ibugbé kan;
12 Ti a nṣe lãlã, a nfi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ: nwọn ngàn wa, awa nsure; nwọn nṣe inunibini si wa, awa nforitì i:
13 Nwọn nkẹgàn wa, awa mbẹ̀bẹ: a ṣe wa bi ohun ẹgbin aiye, bi ẽri ohun gbogbo titi di isisiyi.
14 Emi kò kọ̀we nkan wọnyi lati fi dojutì nyin, ṣugbọn lati kìlọ fun nyin bi awọn ọmọ mi ayanfẹ.
15 Nitori bi ẹnyin tilẹ ni ẹgbarun olukọni ninu Kristi, ṣugbọn ẹnyin kò ni baba pipọ: nitoripe ninu Kristi Jesu ni mo ti fi ihinrere bí nyin.