1 ṢUGBỌN niti awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe gbogbo wa li o ni ìmọ. Ìmọ a mã fẹ̀, ṣugbọn ifẹ ni gbe-ni-ro.
2 Bi ẹnikan ba si rò pe on mọ̀ ohun kan, kò ti imọ̀ bi o ti yẹ ti iba mọ̀.
3 Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba fẹ Ọlọrun, oluwarẹ̀ li o di mimọ̀ fun u.
4 Nitorina niti jijẹ awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe ohun asan li oriṣa li aiye, ati pe kò si Ọlọrun miran bikoṣe ọkanṣoṣo.