6 Ṣugbọn fun awa Ọlọrun kan ni mbẹ, Baba, lọwọ ẹniti ohun gbogbo ti wá, ati ti ẹniti gbogbo wa iṣe; ati Oluwa kanṣoṣo Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ati awa nipasẹ rẹ̀.
7 Ṣugbọn ìmọ yi kò si ninu gbogbo enia: ṣugbọn awọn ẹlomiran ti o ti mbọriṣa pẹ titi fi di isisiyi jẹ ẹ bi ohun ti a fi rubọ si oriṣa; ati ẹri-ọkàn wọn ti o ṣe ailera si di alaimọ́.
8 Ṣugbọn onjẹ ki yio mu wa sunmọ Ọlọrun: nitoripe kì iṣe bi awa ba jẹ li awa san ju; tabi bi awa kò si jẹ li awa buru ju.
9 Ṣugbọn ẹ mã kiyesara ki omnira nyin yi ki o máṣe di ohun ikọsẹ fun awọn ti o ṣe ailera.
10 Nitoripe bi ẹnikan ba ri ti iwọ ti o ni ìmọ ba joko tì onjẹ ni ile oriṣa, bi on ba ṣe alailera, ọkan rẹ̀ kì yio ha duro lati mã jẹ nkan wọnni ti a fi rubọ si oriṣa?
11 Ati nipa ìmọ rẹ li alailera arakunrin, nitori ẹniti Kristi ṣe kú, yio fi ṣegbé?
12 Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣẹ̀ si awọn arakunrin bẹ̃, ti ẹ si npa ọkàn wọn ti iṣe ailera lara, ẹnyin nṣẹ̀ si Kristi.