10 Tabi o nsọ eyi patapata nitori wa? Nitõtọ nitori wa li a ṣe kọwe yi: ki ẹniti ntulẹ ki o le mã tulẹ ni ireti; ati ẹniti npakà, ki o le ni ireti ati ṣe olubapin ninu rẹ̀.
11 Bi awa ba ti funrugbin ohun ti ẹmí fun nyin, ohun nla ha ni bi awa ó ba ká ohun ti nyin ti iṣe ti ara?
12 Bi awọn ẹlomiran ba ṣe alabapin ninu agbara yi lori nyin, awa kọ́ ẹniti o tọ́ fun ju? Ṣugbọn awa kò lò agbara yi; ṣugbọn awa farada ohun gbogbo, ki awa ki o má ba ṣe ìdena fun ihinrere Kristi.
13 Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nṣiṣẹ nipa ohun mimọ́, nwọn a mã jẹ ninu ohun ti tẹmpili? ati awọn ti nduro tì pẹpẹ nwọn ama ṣe ajọpin pẹlu pẹpẹ?
14 Gẹgẹ bẹ̃li Oluwa si ṣe ìlana pe, awọn ti nwasu ihinrere ki nwọn o si ma jẹ nipa ihinrere.
15 Ṣugbọn emi kò lò ọ̀kan ninu nkan wọnyi: bẹ̃li emi kò si kọwe nkan wọnyi, nitori ki a le ṣe bẹ̃ gẹgẹ fun mi: nitoripe o san fun mi ki emi kuku kú, jù ki ẹnikẹni ki o sọ ogo mi di asan.
16 Nitoripe bi mo ti nwasu ihinrere, emi kò li ohun ti emi ó fi ṣogo: nitoripe aigbọdọ-máṣe wà lori mi; ani, mogbé! bi emi kò ba wasu ihinrere.