4 Awa kò ha li agbara lati mã jẹ ati lati mã mu?
5 Awa kò ha li agbara lati mã mu aya ti iṣe arabinrin kiri, gẹgẹ bi awọn Aposteli miran, ati bi awọn arakunrin Oluwa, ati Kefa?
6 Tabi emi nikan ati Barnaba, awa kò ha li agbara lati joko li aiṣiṣẹ?
7 Tani ilọ si ogun nigba kan rí ni inawo ara rẹ̀? tani igbìn ọgba ajara, ti ki isi jẹ ninu eso rẹ̀? tabi tani mbọ́ ọ̀wọ́-ẹran, ti kì isi jẹ ninu wàra ọ̀wọ́-ẹran na?
8 Emi ha nsọ̀rọ nkan wọnyi bi enia? tabi ofin kò wi bakanna pẹlu bi?
9 Nitoriti a ti kọ ọ ninu ofin Mose pe, Iwọ kò gbọdọ pa malu ti npaka li ẹnu mọ́. Iha ṣe malu li Ọlọrun nṣe itọju bi?
10 Tabi o nsọ eyi patapata nitori wa? Nitõtọ nitori wa li a ṣe kọwe yi: ki ẹniti ntulẹ ki o le mã tulẹ ni ireti; ati ẹniti npakà, ki o le ni ireti ati ṣe olubapin ninu rẹ̀.