7 Nitori eyi, ará, awa ni itunu lori nyin ninu gbogbo wahalà ati ipọnju wa nitori igbagbọ́ nyin:
8 Nitori awa yè nisisiyi, bi ẹnyin ba duro ṣinṣin ninu Oluwa.
9 Nitori ọpẹ́ kili awa le tún ma dá lọwọ Ọlọrun nitori nyin, fun gbogbo ayọ̀ ti awa nyọ̀ nitori nyin niwaju Ọlọrun wa;
10 Li ọsán ati li oru li awa ngbadura gidigidi pe, ki awa ki o le ri oju nyin, ki a si ṣe aṣepé eyiti o kù ninu igbagbọ́ nyin?
11 Njẹ ki Ọlọrun ati Baba wa tikararẹ, ati Jesu Kristi Oluwa wa, ṣe amọ̀na wa sọdọ nyin.
12 Ki Oluwa si mã mu nyin bisi i, ki ẹ si mã pọ̀ ninu ifẹ si ọmọnikeji nyin, ati si gbogbo enia, gẹgẹ bi awa ti nṣe si nyin:
13 Ki o ba le fi ọkàn nyin balẹ li ailabukù ninu ìwa mimọ́ niwaju Ọlọrun ati Baba wa, nigba atiwá Jesu Kristi Oluwa wa pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀.