13 Bi mo tilẹ jẹ asọ ọ̀rọ-odì lẹkan rí, ati oninunibini, ati elewu enia: ṣugbọn mo ri ãnu gbà, nitoriti mo ṣe e li aimọ̀ ninu aigbagbọ.
14 Ore-ọfẹ Oluwa wa si pọ̀ rekọja pẹlu igbagbọ́ ati ifẹ, ti mbẹ ninu Kristi Jesu.
15 Otitọ li ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà, pe Kristi Jesu wá si aiye lati gbà ẹlẹṣẹ là; ninu awọn ẹniti emi jẹ pàtaki.
16 Ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe ri ãnu gbà, pe lara mi, bi olori, ni ki Jesu Kristi fi gbogbo ipamọra rẹ̀ hàn bi apẹrẹ fun awọn ti yio gbà a gbọ́ si ìye ainipẹkun nigba ikẹhin.
17 Njẹ fun Ọba aiyeraiye, aidibajẹ, airi, Ọlọrun kanṣoṣo, ni ọlá ati ogo wà fun lai ati lailai. Amin.
18 Aṣẹ yi ni mo pa fun ọ, Timotiu ọmọ mi, gẹgẹ bi isọtẹlẹ wọnni ti o ti ṣaju lori rẹ, pe nipa wọn ki iwọ ki o le mã jà ogun rere;
19 Mã ni igbagbọ́ ati ẹri-ọkàn rere; eyiti awọn ẹlomiran tanu kuro lọdọ wọn ti nwọn si rì ọkọ̀ igbagbọ́ wọn: