1 EMI alàgba si ayanfẹ obinrin ọlọlá ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ti mo fẹ li otitọ; kì si iṣe emi nikan, ṣugbọn gbogbo awọn ti o mọ̀ otitọ pẹlu;
2 Nitori otitọ ti ngbé inu wa, yio si mã ba wa gbé titi.
3 Õre-ọfẹ, ãnu, ati alafia, yio wà pẹlu wa, lati ọdọ Ọlọrun Baba, ati lati ọdọ Jesu Kristi, Ọmọ Baba, ninu otitọ ati ninu ifẹ.
4 Mo yọ̀ gidigidi pe mo ti ri ninu awọn ọmọ rẹ ti nrin ninu otitọ, ani bi awa ti gbà ofin lati ọdọ Baba.
5 Njẹ nisisiyi mo bẹ̀ ọ, obinrin ọlọlá, kì iṣe bi ẹnipe emi nkọwe ofin titun kan si ọ, bikọse eyi ti awa ti ni li àtetekọṣe, pe ki awa ki o fẹràn ara wa.
6 Eyi si ni ifẹ, pe, ki awa ki o mã rìn nipa ofin rẹ̀. Eyi li ofin na, ani bi ẹ ti gbọ́ li àtetekọṣe, pe, ki ẹnyin ki o mã rìn ninu rẹ̀.