2. Pet 1 YCE

Ìkíni

1 SIMONI Peteru, iranṣẹ ati Aposteli Jesu Kristi, si awọn ti o ti gbà irú iyebiye igbagbọ́ kanna pẹlu wa, ninu ododo Ọlọrun wa ati ti Jesu Kristi Olugbala:

2 Ki ore-ọfẹ ati alafia ki o mã bisi i fun nyin ninu ìmọ Ọlọrun, ati ti Jesu Oluwa wa,

Ìpè ati Yíyàn Onigbagbọ

3 Bi agbara rẹ̀ bi Ọlọrun ti fun wa li ohun gbogbo ti iṣe ti ìye ati ti ìwa-bi-Ọlọrun, nipa ìmọ ẹniti o pè wa nipa ogo ati ọlanla rẹ̀:

4 Nipa eyiti o ti fi awọn ileri rẹ̀ ti o tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa: pe nipa iwọnyi ni ki ẹnyin ki o le di alabapin ninu ìwa Ọlọrun, nigbati ẹnyin bá ti yọ kuro ninu ibajẹ ti mbẹ ninu aiye nipa ifẹkufẹ.

5 Ati nitori eyi nã pãpã, ẹ mã ṣe aisimi gbogbo, ẹ fi ìwarere kún igbagbọ́, ati ìmọ kún ìwarere;

6 Ati airekọja kún ìmọ; ati sũru kún airekọja; ati ìwa-bi-Ọlọrun kún sũru;

7 Ati ifẹ ọmọnikeji kún ìwa-bi-Ọlọrun; ati ifẹni kún ifẹ ọmọnikeji.

8 Nitori bi ẹnyin bá ni nkan wọnyi ti nwọn bá si pọ̀, nwọn kì yio jẹ ki ẹ ṣe ọ̀lẹ tabi alaileso ninu ìmọ Oluwa wa Jesu Kristi.

9 Nitori ẹniti o ba ṣe alaini nkan wọnyi, o fọju, kò le riran li òkẽre, o si ti gbagbé pe a ti wẹ̀ on nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ atijọ.

10 Nitorina, ará, ẹ tubọ mã ṣe aisimi lati sọ ìpe ati yiyàn nyin di dajudaju: nitori bi ẹnyin ba nṣe nkan wọnyi, ẹnyin kì yio kọsẹ lai.

11 Nitori bayi li a ó pese fun nyin lọpọlọpọ lati wọ ijọba ainipẹkun ti Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi.

12 Nitorina emi ó mã mura lati mã mu nkan wọnyi wá si iranti nyin nigbagbogbo bi ẹnyin tilẹ ti mọ̀ wọn, ti ẹsẹ nyin si mulẹ ninu otitọ ti ẹnyin ni.

13 Emi si rò pe o yẹ, niwọn igbati emi ba mbẹ ninu agọ́ yi, lati mã fi iranti rú nyin soke;

14 Bi emi ti mọ̀ pe, bibọ́ agọ́ mi yi silẹ kù si dẹdẹ, ani bi Oluwa wa Jesu Kristi ti fihàn mi.

15 Emi o si mã ṣãpọn pẹlu, ki ẹnyin ki o le mã ranti nkan wọnyi nigbagbogbo lẹhin ikú mi.

Ògo Kristi ati Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀

16 Nitori ki iṣe bi ẹniti ntọ ìtan asan lẹhin ti a fi ọgbọ́n-kọgbọn là silẹ, li awa fi agbara ati wíwá Jesu Kristi Oluwa wa hàn nyin, ṣugbọn ẹlẹri ọlá nla rẹ̀ li awa iṣe.

17 Nitoriti o gbà ọlá on ogo lati ọdọ Ọlọrun Baba, nigbati irú ohùn nì fọ̀ si i lati inu ogo nla na wá pe, Eyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si jọjọ.

18 Ohùn yi ti o ti ọrun wá li awa si gbọ́, nigbati awa mbẹ pẹlu rẹ̀ lori òke mimọ́ na.

19 Awa si ni ọ̀rọ asọtẹlẹ ti o fẹsẹmulẹ jubẹ̃lọ; eyiti o yẹ ki ẹ kiyesi bi fitila ti ntàn ni ibi òkunkun, titi ilẹ yio fi mọ́, ti irawọ owurọ̀ yio si yọ li ọkàn nyin.

20 Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi, pe kò si ọ̀kan ninu asọtẹlẹ inu iwe-mimọ́ ti o ni itumọ̀ ikọkọ.

21 Nitori asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ enia wá ri; ṣugbọn awọn enia nsọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ wá.

orí

1 2 3