1 OLUFẸ, eyi ni iwe keji ti mo nkọ si nyin; ninu mejeji na li emi nrú inu funfun nyin soke nipa riran nyin leti:
2 Ki ẹnyin ki o le mã ranti ọ̀rọ ti a ti ẹnu awọn woli mimọ́ sọ ṣaju, ati ofin Oluwa ati Olugbala wa lati ọdọ awọn aposteli nyin:
3 Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi pe, nigba ọjọ ikẹhin, awọn ẹlẹgan yio de pẹlu ẹgan wọn, nwọn o mã rin nipa ifẹ ara wọn,
4 Nwọn o si mã wipe, Nibo ni ileri wíwa rẹ̀ gbé wà? lati igbati awọn baba ti sùn, ohun gbogbo nlọ bi nwọn ti wà rí lati ìgba ọjọ ìwa.
5 Nitori eyi ni nwọn mọ̃mọ ṣe aifẹ̃mọ, pe nipa ọ̀rọ Ọlọrun li awọn ọrun ti wà lati ìgba atijọ, ati ti ilẹ yọri jade ninu omi, ti o si duro ninu omi:
6 Nipa eyi ti omi bo aiye ti o wà nigbana, ti o si ṣegbe:
7 Ṣugbọn awọn ọrun ati aiye, ti mbẹ nisisiyi, nipa ọ̀rọ kanna li a ti tojọ bi iṣura fun iná, a pa wọn mọ́ dè ọjọ idajọ ati iparun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun.
8 Ṣugbọn, olufẹ, ẹ máṣe gbagbe ohun kan yi, pe ọjọ kan lọdọ Oluwa bi ẹgbẹ̀run ọdún li o ri, ati ẹgbẹ̀run ọdún bi ọjọ kan.
9 Oluwa kò fi ileri rẹ̀ jafara, bi awọn ẹlomiran ti ikà a si ijafara; ṣugbọn o nmu sũru fun nyin nitori kò fẹ ki ẹnikẹni ki o ṣegbé, bikoṣe ki gbogbo enia ki o wá si ironupiwada.
10 Ṣugbọn ọjọ Oluwa mbọ̀wá bi olè li oru; ninu eyi ti awọn ọrun yio kọja lọ ti awọn ti ariwo nla, ati awọn imọlẹ oju ọrun yio si ti inu oru gbigbona gidigidi di yíyọ, aiye ati awọn iṣẹ ti o wà ninu rẹ̀ yio si jóna lulu.
11 Njẹ bi gbogbo nkan wọnyi yio ti yọ́ nì, irú enia wo li ẹnyin iba jẹ ninu ìwa mimọ́ gbogbo ati ìwa-bi-Ọlọrun,
12 Ki ẹ mã reti, ki ẹ si mã mura giri de díde ọjọ Ọlọrun, nitori eyiti awọn ọ̀run yio gbiná, ti nwọn yio di yíyọ́, ti awọn imọlẹ rẹ̀ yio si ti inu õru gbigbona gidigidi di yíyọ?
13 Ṣugbọn gẹgẹ bi ileri rẹ̀, awa nreti awọn ọrun titun ati aiye titun, ninu eyiti ododo ngbé.
14 Nitorina, olufẹ, bi ẹnyin ti nreti irú nkan wọnyi, ẹ mura giri, ki a le bá nyin li alafia, li ailabawọn, ati li ailàbuku li oju rẹ̀.
15 Ki ẹ si mã kà a si pe, sũru Oluwa wa igbala ni; bi Paulu pẹlu, arakunrin wa olufẹ, ti kọwe si nyin, gẹgẹ bi ọgbọ́n ti a fifun u;
16 Bi o ti nsọ̀rọ nkan wọnyi pẹlu ninu iwe rẹ̀ gbogbo; ninu eyi ti ohun miran ti o ṣòro lati yéni gbé wà, eyiti awọn òpè ati awọn alaiduro nibikan nlọ́, bi nwọn ti nlọ́ iwe mimọ́ iyoku, si iparun ara wọn.
17 Nitorina ẹnyin olufẹ, bi ẹnyin ti mọ̀ nkan wọnyi tẹlẹ ẹ mã kiyesara, ki a má ba fi ìṣina awọn enia buburu fà nyin lọ, ki ẹ si ṣubu kuro ni iduro ṣinṣin nyin.
18 Ṣugbọn ẹ mã dàgba ninu õre-ọfẹ ati ninu ìmọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun nisisiyi ati titi lai. Amin.