33 Gbogbo ilu si pejọ li ẹnu-ọ̀na.
34 O si wò ọ̀pọ awọn ti o ni onirũru àrun sàn, o si lé ọ̀pọ ẹmi èṣu jade; ko si jẹ ki awọn ẹmi èṣu na ki o fọhun, nitoriti nwọn mọ̀ ọ.
35 O si dide li owurọ̀ ki ilẹ to mọ́, o si jade lọ si ibi iju kan, nibẹ li o si ngbadura.
36 Simoni ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si nwá a.
37 Nigbati nwọn si ri i, nwọn wi fun u pe, Gbogbo enia nwá ọ.
38 O si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ilu miran, ki emi ki o le wasu nibẹ̀ pẹlu: nitori eyi li emi sá ṣe wá.
39 O si nwãsu ninu sinagogu wọn lọ ni gbogbo Galili, o si nlé awọn ẹmi èṣu jade.