Mak 13 YCE

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Wíwó Tẹmpili

1 BI o si ti nti tẹmpili jade, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wipe, Olukọni, wò irú okuta ati irú ile ti o wà nihinyi!

2 Jesu si dahùn wi fun u pe, Iwọ ri ile nla wọnyi? kì yio si okuta kan ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a kì yio wó lulẹ.

Ìbẹ̀rẹ̀ Ìrora

3 Bi o si ti joko lori òke Olifi ti o kọju si tẹmpili, Peteru ati Jakọbu, ati Johanu ati Anderu, bi i lẽre nikọ̀kọ wipe,

4 Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? kini yio si ṣe àmi nigbati gbogbo nkan wọnyi yio ṣẹ?

5 Jesu si da wọn lohùn, o bẹ̀rẹ si isọ fun wọn pẹ, Ẹ mã kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ:

6 Nitori awọn enia pipọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn o si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ.

7 Nigbati ẹnyin ba si ngburó ogun ati idagìri ogun; ki ẹnyin ki o máṣe jaiya: nitori irú nkan wọnyi kò le ṣe ki o ma ṣẹ; ṣugbọn opin na kì iṣe isisiyi.

8 Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ede, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: isẹlẹ yio si wà ni ibi pupọ, ìyan yio si wà ati wahalà: nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju.

9 Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin: nitori nwọn ó si fi nyin le awọn igbimọ lọwọ; a o si lù nyin ninu sinagogu: a o si mu nyin duro niwaju awọn balẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn.

10 A kò le ṣaima kọ́ wasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ède.

11 Ṣugbọn nigbati nwọn ba nfà nyin, lọ, ti nwọn ba si nfi nyin le wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣaniyan ṣaju ohun ti ẹ o sọ; ṣugbọn ohun ti a ba fifun nyin ni wakati na, on ni ki ẹnyin ki o wi: nitori kì iṣe ẹnyin ni nwi, bikoṣe Ẹmí Mimọ́.

12 Arakunrin yio si fi arakunrin fun pipa, ati baba yio fi ọmọ rẹ̀ hàn; awọn ọmọ yio si dide si obi wọn, nwọn o si mu ki a pa wọn.

13 Gbogbo enia ni yio si korira nyin nitori orukọ mi: ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na li a o gbalà.

Àkókò Ìpọ́njú Ńlá

14 Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro nì, ti o duro nibiti ko tọ́, ti a ti ẹnu woli Danieli ṣọ, (ẹnikẹni ti o ba kà a, ki o yé e,) nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea sálọ si ori òke:

15 Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o máṣe sọkalẹ lọ sinu ile, bẹ̃ni ki o má si ṣe wọ̀ inu rẹ̀, lati mu ohunkohun jade ninu ile rẹ̀:

16 Ati ki ẹniti mbẹ li oko ki o maṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ̀.

17 Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmu fun ọmọ mu li ọjọ wọnni!

18 Ki ẹ si ma gbadura, ki sisá nyin ki o máṣe bọ́ si igba otutù.

19 Nitori ọjọ wọnni, yio jẹ ọjọ ipọnju irú eyi ti kò si lati igba ọjọ ìwa ti Ọlọrun da, titi fi di akokò yi, irú rẹ̀ ki yio si si.

20 Bi ko si ṣe bi Oluwa ti ke ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le là: ṣugbọn nitoriti awọn ayanfẹ ti o ti yàn, o ti ke ọjọ wọnni kuru.

21 Nitorina bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, wo o, Kristi mbẹ nihinyi; tabi, wo o, o mbẹ lọ́hun; ẹ máṣe gbà a gbọ́:

22 Nitori awọn eke Kristi, ati awọn eke woli yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu hàn, tobẹ̃ bi o ṣe iṣe, nwọn iba tàn awọn ayanfẹ pãpã.

23 Ṣugbọn ẹ kiyesara: wo o, mo sọ ohun gbogbo fun nyin tẹlẹ.

Dídé Ọmọ-Eniyan

24 Ṣugbọn li ọjọ wọnni, lẹhin ipọnju na, õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọle rẹ̀ hàn;

25 Awọn irawọ oju ọrun yio já silẹ̀, ati agbara ti mbẹ li ọrun li a o si mì titi.

26 Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara nla ati ogo.

27 Nigbana ni yio si rán awọn angẹli rẹ̀, yio si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun aiye titi de ikangun ọrun.

Ẹ̀kọ́ Lára Igi Ọ̀pọ̀tọ́

28 Nisisiyi ẹ kọ́ owe lara igi ọpọtọ; Nigbati ẹ̀ka rẹ̀ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ̀ pe igba ẹ̃rùn sunmọ etile:

29 Gẹgẹ bẹ̃ na li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri nkan wọnyi ti nṣẹ, ki ẹ mọ̀ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun.

30 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Iran yi kì yio rekọja, titi a o fi mu gbogbo nkan wọnyi ṣẹ.

31 Ọrun on aiye yio rekọja: ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja.

Nígbà Wo ni Àkókò Náà?

32 Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, kò si, ki tilẹ iṣe awọn angẹli ọrun, tabi Ọmọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo.

33 Ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã gbadura: nitori ẹnyin ko mọ̀ igbati akokò na yio de.

34 Nitori Ọmọ-enia dabi ọkunrin kan ti o lọ si àjo ti o jìna rére, ẹniti o fi ile rẹ̀ silẹ, ti o si fi aṣẹ fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iṣẹ olukuluku fun u, ti o si fi aṣẹ fun oluṣọna ki o mã ṣọna.

35 Nitorina ẹ mã ṣọna: nitori ẹnyin ko mọ̀ igba ti bãle ile mbọ̀wá, bi li alẹ ni, tabi larin ọganjọ, tabi li akukọ, tabi li owurọ̀:

36 Pe, nigbati o ba de li ojijì, ki o máṣe ba nyin li oju orun.

37 Ohun ti mo wi fun nyin, mo wi fun gbogbo enia, Ẹ mã ṣọna.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16