Mak 8 YCE

Jesu Bọ́ Ẹgbaaji (4,000) Eniyan

1 LI ọjọ wọnni nigbati ijọ enia pọ̀ gidigidi, ti nwọn ko si li onjẹ, Jesu pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe,

2 Ãnu ijọ enia nṣe mi, nitoriti o di ijọ mẹta nisisiyi ti nwọn ti wà lọdọ mi, nwọn kò si li ohun ti nwọn o jẹ:

3 Bi emi ba si rán wọn lọ si ile wọn li ebi, ãrẹ̀ yio mu wọn li ọ̀na: nitori ninu wọn ti ọ̀na jijìn wá.

4 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si da a lohùn wipe, Nibo li a ó gbé ti le fi akara tẹ́ awọn enia wọnyi lọrùn li aginjù yi?

5 O si bi wọn lẽre, wipe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? Nwọn si wipe, Meje.

6 O si paṣẹ ki awọn enia joko ni ilẹ: o si mu iṣu akara meje na, o dupẹ, o bu u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju wọn; nwọn si gbé e kalẹ niwaju awọn enia.

7 Nwọn si li ẹja kekeke diẹ: o si sure, o si ni ki a fi wọn siwaju wọn pẹlu.

8 Nwọn si jẹ, nwọn si yó: nwọn si kó ajẹkù ti o kù jọ agbọ̀n meje.

9 Awọn ti o jẹ ẹ to ìwọn ẹgbãji enia: o si rán wọn lọ.

10 Lojukanna, o si wọ̀ ọkọ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wá si apa ìha Dalmanuta.

Àwọn Farisi ń fẹ́ Àmì

11 Awọn Farisi si jade wá, nwọn bẹrẹ si bi i lẽre, nwọn nfẹ àmi lati ọrun wá lọwọ rẹ̀, nwọn ndán a wò.

12 O si kẹdùn gidigidi ninu ọkàn rẹ̀, o si wipe, Ẽṣe ti iran yi fi nwá àmi? lõtọ ni mo wi fun nyin, Ko si àmi ti a o fifun iran yi.

13 O si fi wọn silẹ o si tún bọ sinu ọkọ̀ rekọja lọ si apa ekeji.

Ìwúkàrà Àwọn Farisi ati Ti Hẹrọdu

14 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbagbé lati mu akara lọwọ, nwọn kò si ni jù iṣu akara kan ninu ọkọ̀ pẹlu wọn.

15 O si kìlọ fun wọn, wipe, Ẹ kiyesara, ki ẹ ma ṣọra nitori iwukara awọn Farisi ati iwukara Herodu.

16 Nwọn si mba ara wọn ṣe aroye, wipe, Nitoriti awa kò mu akara lọwọ ni.

17 Nigbati Jesu si mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣàroye pe ẹnyin ko ni akara lọwọ? ẹnyin ko ti ikiyesi titi di isisiyi, ẹ ko si ti iwoye, ẹnyin si li ọkàn lile titi di isisiyi?

18 Ẹnyin li oju ẹnyin kò si riran? ẹnyin li etí, ẹnyin kò si gbọran? ẹnyin kò si ranti?

19 Nigbati mo bu iṣu akara marun larin ẹgbẹdọgbọn enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wi fun u pe, Mejila.

20 Ati nigba iṣu akara meje larin ẹgbaji enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wipe, Meje.

21 O si wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti kò fi yé nyin?

Jesu Wo Afọ́jú kan Sàn ní Bẹtisaida

22 O si wá si Betsaida; nwọn si mu afọju kan wá sọdọ rẹ̀, nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o fi ọwọ́ kàn a.

23 O si mu afọju na li ọwọ́, o si fà a jade lọ sẹhin ilu; nigbati o si tutọ́ si i loju, ti o si gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, o bi i lẽre bi o ri ohunkohun.

24 O si wòke, o si wipe, Mo ri awọn enia dabi igi, nwọn nrìn.

25 Lẹhin eyini o si tún fi ọwọ́ kàn a loju, o si mu ki o wòke: o si sàn, o si ri gbogbo enia gbangba.

26 O si rán a pada lọ si ile rẹ̀, wipe, Máṣe lọ si ilu, ki o má si sọ ọ fun ẹnikẹni ni ilu.

Peteru Jẹ́wọ́ Ẹni Tí Jesu Í Ṣe

27 Jesu si jade, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ si awọn ileto Kesarea Filippi: o si bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẽre li ọna nwi fun wọn pe, Tali awọn enia nfi mi pè?

28 Nwọn si dahùn wipe, Johanu Baptisti: ẹlomiran si wipe Elijah; ṣugbọn awọn ẹlomiran wipe, Ọkan ninu awọn woli.

29 O si bi wọn pe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi mi pè? Peteru si dahùn o si wi fun u pe, Iwọ ni Kristi na.

30 O si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ̀rọ on fun ẹnikan.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀

31 O si bẹ̀rẹ si ikọ́ wọn, pe, Ọmọ-enia ko le ṣaima jìya ohun pipọ, a o si kọ̀ ọ lati ọdọ awọn àgbagba ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, a o si pa a, lẹhin ijọ mẹta yio si jinde.

32 O si sọ ọ̀rọ na ni gbangba. Peteru si mu u, o bẹ̀rẹ si iba a wi.

33 Ṣugbọn o yipada o si wò awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si ba Peteru wi, o ni, Kuro lẹhin mi, Satani: nitori iwọ ko ro ohun ti Ọlọrun bikoṣe ohun ti enia.

34 O si pè ijọ enia sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wi fun wọn pe Bi ẹnikẹni ba fẹ tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.

35 Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmí rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi ati nitori ihinrere, on na ni yio gbà a là.

36 Nitoripe ère kini fun enia, bi o jère gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmi rẹ̀ nù?

37 Tabi kili enia iba fi ṣe paṣiparọ ẹmi rẹ̀?

38 Nitori ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọ̀rọ mi, ni iran panṣaga ati ẹlẹsẹ yi, on na pẹlu li Ọmọ-enia yio tiju rẹ̀, nigbati o ba de ninu ogo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli mimọ́.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16