Mak 11 YCE

Jesu fi Ẹ̀yẹ wọ Jerusalẹmu

1 NIGBATI nwọn si sunmọ eti Jerusalemu, leti Betfage ati Betani, li òke Olifi, o rán meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀,

2 O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si iletò ti o kọju si nyin: lojukanna bi ẹnyin ti nwọ̀ inu rẹ̀ lọ, ẹnyin ó si ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan ti a so, ti ẹnikẹni ko gùn rì; ẹ tú u, ki é si fà a wá.

3 Bi ẹnikẹni ba si wi fun nyin pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe eyi? ẹ wipe, Oluwa ni fi ṣe; lojukanna yio si rán a wá sihinyi.

4 Nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ na ti a so li ẹnu-ọ̀na lode ni ita gbangba; nwọn si tú u.

5 Awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nṣe, ti ẹnyin fi ntú ọmọ kẹtẹkẹtẹ nì?

6 Nwọn si wi fun wọn gẹgẹ bi Jesu ti wi fun wọn: nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ.

7 Nwọn si fà ọmọ kẹtẹkẹtẹ na tọ̀ Jesu wá, nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹ̀hin rẹ̀; on si joko lori rẹ̀.

8 Awọn pipọ si tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na: ati awọn miran ṣẹ́ ẹ̀ka igi, nwọn si fún wọn si ọ̀na.

9 Ati awọn ti nlọ niwaju, ati awọn ti mbọ̀ lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna; Olubukun li ẹniti o mbọ̀wá li orukọ Oluwa:

10 Olubukun ni ijọba ti mbọ̀wá, ijọba Dafidi, baba wa: Hosanna loke ọrun.

11 Jesu si wọ̀ Jerusalemu, ati tẹmpili. Nigbati o si wò ohun gbogbo yiká, alẹ sa ti lẹ tan, o si jade lọ si Betani pẹlu awọn mejila.

Jesu Fi Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Gégùn-ún

12 Ni ijọ keji, nigbati nwọn ti Betani jade, ebi si npa a:

13 O si ri igi ọpọtọ kan li òkere ti o li ewé, o wá, bi bọya on le ri ohun kan lori rẹ̀: nigbati o si wá si idi rẹ̀, ko ri ohun kan, bikoṣe ewé; nitori akokò eso ọpọtọ kò ti ito.

14 Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Ki ẹnikẹni má jẹ eso lori rẹ mọ́ titi lai. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbọ́ ọ.

Jesu Lòdì sí Lílò tí Wọn Ń Lo Tẹmpili Bí Ọjà

15 Nwọn si wá si Jerusalemu: Jesu si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o bẹ̀rẹ si ilé awọn ti ntà ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si tari tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle.

16 Kò si jẹ ki ẹnikẹni ki o gbe ohun èlo kọja larin tẹmpili.

17 O si nkọ́ni, o nwi fun wọn pe, A ko ti kọwe rẹ̀ pe, Ile adura fun gbogbo orilẹ-ède li a o ma pè ile mi? ṣugbọn ẹnyin ti ṣọ di ihò awọn ọlọsà.

18 Awọn akọwe ati awọn olori alufa si gbọ́, nwọn si nwá ọ̀na bi nwọn o ti ṣe pa a run: nitori nwọn bẹ̀ru rẹ̀, nitori ẹnu yà gbogbo ijọ enia si ẹkọ́ rẹ̀.

19 Nigbati alẹ ba si lẹ, a jade kuro ni ilu.

Ẹ̀kọ́ Lára Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Tí Ó Gbẹ

20 Bi nwọn si ti nkọja lọ li owurọ, nwọn ri igi ọpọtọ na gbẹ ti gbongbo ti gbongbo.

21 Peteru si wa iranti o wi fun u pe, Rabbi, wò bi igi ọpọtọ ti iwọ fi bú ti gbẹ.

22 Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ ni igbagbọ́ si Ọlọrun.

23 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ sinu okun; ti kò ba si ṣiyemeji li ọkàn rẹ̀, ṣugbọn ti o ba gbagbọ́ pe ohun ti on wi yio ṣẹ, yio ri bẹ̃ fun u.

24 Nitorina mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura, ẹ gbagbọ́ pe ẹ ti ri wọn gbà na, yio si ri bẹ̃ fun nyin.

25 Nigbati ẹnyin ba si duro ngbadura, ẹ darijì, bi ẹnyin ba ni ohunkohun si ẹnikẹni: ki Baba nyin ti mbẹ li ọrun ba le dari ẹṣẹ nyin jì nyin pẹlu.

26 Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba dariji, Baba nyin ti mbẹ li ọrun kì yio si dari ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin.

Ìbéèrè Nípa Àṣẹ tí Jesu Ń Lò

27 Nwọn si tún wá si Jerusalemu: bi o si ti nrìn kiri ni tẹmpili, awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn agbàgba, tọ̀ ọ wá,

28 Nwọn si wi fun u pe, Aṣẹ wo li o fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi lati mã ṣe nkan wọnyi?

29 Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi ó bi nyin lẽre ọ̀rọ kan, ki ẹ si da mi lohùn, emi o si sọ fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.

30 Baptismu Johanu lati ọrun wá ni, tabi lati ọdọ enia? ẹ da mi lohùn.

31 Nwọn si ba ara wọn gbèro, wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni: on o wipe, Ẽha ti ṣe ti ẹnyin ko fi gbà a gbọ́?

32 Ṣugbọn bi awa ba wipe, Lati ọdọ enia; nwọn bẹ̀ru awọn enia: nitori gbogbo enia kà Johanu si woli nitõtọ.

33 Nwọn si dahùn wi fun Jesu pe, Awa kó mọ̀. Jesu si dahùn wi fun wọn pe, Emi kì yio si wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16