4 Nwọn si wipe, Mose yọda fun wa lati kọ iwe ikọsilẹ fun u, ki a si fi i silẹ.
5 Jesu si da wọn lohùn, o si wi fun wọn pe, Nitori lile àiya nyin li o ṣe kọ irú ofin yi fun nyin.
6 Ṣugbọn lati igba ti aiye ti ṣẹ, Ọlọrun da wọn ti akọ ti abo.
7 Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ ti yio si faramọ aya rẹ̀;
8 Awọn mejeji a si di ara kan: nitorina nwọn kì iṣe meji mọ́, bikoṣe ara kan.
9 Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn.
10 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tun bi i lẽre ọ̀ran kanna ninu ile.