14 Nigbati nwọn si de, nwọn wi fun u pe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ bẹ̃ni iwọ kì iwoju ẹnikẹni: nitori iwọ kì iṣe ojuṣãju enia, ṣugbọn iwọ nkọ́ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ: O tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́?
15 Ki awa ki o fifun u, tabi ki a má fifun u? Ṣugbọn Jesu mọ̀ agabagebe wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò? ẹ mu owo-idẹ kan fun mi wá ki emi ki o wò o.
16 Nwọn si mu u wá. O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi? Nwọn si wi fun u pe, Ti Kesari ni.
17 Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti Ọlọrun fun Ọlọrun. Ẹnu si yà wọn si i gidigidi.
18 Awọn Sadusi si tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si; nwọn si bi i lẽre, wipe,
19 Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, ti o ba si fi aya silẹ, ti kò si fi ọmọ silẹ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o si gbe iru-ọmọ dide fun arakunrin rẹ̀.
20 Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: eyi ekini si gbé iyawo, o si kú lai fi ọmọ silẹ.