29 Ṣugbọn Peteru wi fun u pe, Bi gbogbo enia tilẹ kọsẹ̀, ṣugbọn emi kọ́.
30 Jesu si wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ pe, loni yi, ani li alẹ yi, ki akukọ ki o to kọ nigba meji, iwọ o sẹ́ mi nigba mẹta.
31 Ṣugbọn o tẹnumọ ọ gidigidi wipe, Bi o tilẹ di ati ba ọ kú, emi ko jẹ sẹ́ ọ bi o ti wù ki o ri. Gẹgẹ bẹ̃ni gbogbo wọn wi pẹlu.
32 Nwọn si wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane: o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi, nigbati mo ba lọ igbadura.
33 O si mu Peteru ati Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀, ẹnu si bẹrẹ si yà a gidigidi, o si bẹré si rẹ̀wẹsi.
34 O si wi fun wọn pẹ, Ọkàn mi nkãnu gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihin, ki ẹ si mã ṣọna.
35 O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ, o si gbadura pe, bi o ba le ṣe, ki wakati na le kọja kuro lori rẹ̀.