3 Nwọn si wá sọdọ rẹ̀, nwọn gbé ẹnikan ti o li ẹ̀gba tọ̀ ọ wá, ẹniti mẹrin gbé.
4 Nigbati nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia, nwọn si ṣí orule ile nibiti o gbé wà: nigbati nwọn si da a lu tan, nwọn sọ akete na kalẹ lori eyiti ẹlẹgba na dubulẹ.
5 Nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọ, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.
6 Ṣugbọn awọn kan ninu awọn akọwe wà ti nwọn joko nibẹ̀, nwọn si ngbèro li ọkàn wọn, wipe,
7 Ẽṣe ti ọkunrin yi fi sọrọ bayi? o nsọ ọrọ-odi; tali o le dari eṣẹ jìni bikoṣe ẹnikan, aní Ọlọrun?
8 Lojukanna bi Jesu ti woye li ọkàn rẹ̀ pe, nwọn ngbèro bẹ̃ ninu ara wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nrò nkan wọnyi ninu ọkàn nyin?
9 Ewo li o ya jù lati wi fun ẹlẹgba na pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si ma rìn?