16 Awọn ti o ri i si ròhin fun wọn bi o ti ri fun ẹniti o li ẹmi èṣu, ati ti awọn ẹlẹdẹ pẹlu.
17 Nwọn si bẹ̀rẹ si ibẹ̀ ẹ, wipe, ki o lọ kuro li àgbegbe wọn.
18 Bi o si ti nwọ̀ inu ọkọ̀, ẹniti o ti li ẹmi èṣu na o mbẹ ẹ, ki on ki o le mã bá a gbé.
19 Ṣugbọn Jesu kò gbà fun u, ṣugbọn o wi fun u pe, Lọ si ile rẹ ki o si sọ fun awọn ará ile rẹ, bi Oluwa ti ṣe ohun nla fun ọ, ati bi o si ti ṣanu fun ọ.
20 O si pada lọ, o bẹ̀rẹ si ima ròhin ni Dekapoli, ohun nla ti Jesu ṣe fun u: ẹnu si yà gbogbo enia.
21 Nigbati Jesu si tun ti inu ọkọ̀ kọja si apa keji, ọ̀pọ enia pejọ tì i: o si wà leti okun.
22 Si wo o, ọkan ninu awọn olori sinagogu, ti a npè ni Jairu, wa sọdọ rẹ̀; nigbati o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀,