30 Lọgan Jesu si ti mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, aṣẹ ti ara on jade, o yipada larin ọpọ enia, o si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi li aṣọ?
31 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Iwọ ri bi ijọ enia ti nhá ọ li àye, iwọ si nwipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi?
32 O si wò yiká lati ri ẹniti o ṣe nkan yi.
33 Ṣugbọn obinrin na ni ibẹ̀ru ati iwarìri, bi o ti mọ̀ ohun ti a ṣe lara on, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ gbogbo otitọ fun u.
34 O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia, ki iwọ ki o si sàn ninu arun rẹ.
35 Bi o si ti nsọ̀rọ li ẹnu, awọn kan ti ile olori sinagogu wá ti o wipe, Ọmọbinrin rẹ kú: ẽṣe ti iwọ si fi nyọ olukọni lẹnu?
36 Lojukanna bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ na ti a sọ, o si wi fun olori sinagogu na pe, Má bẹ̀ru, sá gbagbọ́ nikan.