32 O si wò yiká lati ri ẹniti o ṣe nkan yi.
33 Ṣugbọn obinrin na ni ibẹ̀ru ati iwarìri, bi o ti mọ̀ ohun ti a ṣe lara on, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ gbogbo otitọ fun u.
34 O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia, ki iwọ ki o si sàn ninu arun rẹ.
35 Bi o si ti nsọ̀rọ li ẹnu, awọn kan ti ile olori sinagogu wá ti o wipe, Ọmọbinrin rẹ kú: ẽṣe ti iwọ si fi nyọ olukọni lẹnu?
36 Lojukanna bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ na ti a sọ, o si wi fun olori sinagogu na pe, Má bẹ̀ru, sá gbagbọ́ nikan.
37 Kò si jẹ ki ẹnikẹni tọ̀ on lẹhin, bikoṣe Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu arakunrin Jakọbu.
38 O si wá si ile olori sinagogu, o si ri ariwo, ati awọn ti nsọkun ti nwọn si npohunrere ẹkún gidigidi.