6 Ṣugbọn nigbati o ri Jesu li òkere, o sare wá, o si foribalẹ fun u,
7 O si nkigbe li ohùn rara, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ, ki iwọ ki o máṣe da mi loró.
8 Nitoriti o wi fun u pe, Jade kuro lara ọkunrin na, iwọ ẹmi aimọ́.
9 O si bi i lẽre pe, Orukọ rẹ? O si dahùn, wipe, Legioni li orukọ mi: nitori awa pọ̀.
10 O si bẹ̀ ẹ gidigidi pe, ki o máṣe rán wọn jade kuro ni ilẹ na.
11 Agbo ọ̀pọ ẹlẹdẹ kan si wà nibẹ ti njẹ lẹba oke.
12 Gbogbo awọn ẹmi èṣu bẹ̀ ẹ wipe, Rán wa lọ sinu awọn ẹlẹdẹ, ki awa ki o le wọ̀ inu wọn lọ.