41 Nigbati o si mu iṣu akara marun ati ẹja meji na, o gbé oju soke, o si sure, o si bù iṣu akara na, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju wọn; ati awọn ẹja meji na li o si pín fun gbogbo wọn.
42 Gbogbo wọn si jẹ, nwọn si yó.
43 Nwọn si kó agbọ̀n mejila kún fun ajẹkù, ati ti ẹja pẹlu.
44 Awọn ti o si jẹ ìṣu akara na to iwọn ẹgbẹdọgbọn ọkunrin.
45 Lojukanna li o si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o si ṣiwaju lọ si apa keji si Betsaida, nigbati on tikararẹ̀ tú awọn enia ká.
46 Nigbati o si rán wọn lọ tan, o gùn ori òke lọ igbadura.
47 Nigbati alẹ si lẹ, ọkọ̀ si wà larin okun, on nikan si wà ni ilẹ.