8 Nitoriti ẹnyin fi ofin Ọlọrun si apakan, ẹnyin nfiyesi ofin atọwọdọwọ ti enia, bi irú wiwẹ̀ ohun-èlo ati ago: ati irú ohun miran pipọ bẹ̃ li ẹnyin nṣe.
9 O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin kọ̀ ofin Ọlọrun silẹ, ki ẹnyin ki o le pa ofin atọwọdọwọ ti nyin mọ́.
10 Mose sá wipe, Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ; ati Ẹnikẹni ti o ba sọrọ baba tabi iya rẹ̀ ni buburu, ẹ jẹ ki o kú ikú rẹ̀ na:
11 Ṣugbọn ẹnyin wipe, Bi enia ba wi fun baba tabi iya rẹ̀ pe, ohunkohun ti iwọ iba fi jère lara mi, Korbani ni, eyini ni Ẹbùn, o bọ́.
12 Bẹ̃li ẹnyin ko si jẹ ki o ṣe ohunkohun fun baba tabi iya rẹ̀ mọ́;
13 Ẹnyin nfi ofin atọwọdọwọ ti nyin, ti ẹ fi le ilẹ, sọ ọ̀rọ Ọlọrun di asan; ati ọpọ iru nkan bẹ̃ li ẹnyin nṣe.
14 Nigbati o si pè gbogbo awọn enia sọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ fi etí si mi olukuluku nyin, ẹ si kiyesi i: