1 O si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹlomiran wà ninu awọn ti o duro nihinyi, ti kì yio tọ́ iku wò, titi nwọn o fi ri ti ijọba Ọlọrun yio fi de pẹlu agbara.
2 Lẹhin ijọ mẹfa Jesu si mu Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, o si mu wọn lọ sori òke giga li apakan awọn nikan: ara rẹ̀ si yipada niwaju wọn.
3 Aṣọ rẹ̀ si di didán, o si funfun gidigidi; afọṣọ kan li aiye kò le fọ̀ aṣọ fún bi iru rẹ̀.
4 Elijah pẹlu Mose si farahàn fun wọn: nwọn si mba Jesu sọ̀rọ.
5 Peteru si dahùn o si wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa lati ma gbé ihinyi: si jẹ ki a pa agọ́ mẹta, ọkan fun ọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah.
6 On kò sá mọ̀ eyi ti iba wi; nitori ẹ̀ru bà wọn gidigidi.
7 Ikuku kan si wá, o ṣiji bò wọn; ohùn kan si ti inu ikuku na wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀.