16 O si bi awọn akọwe, wipe, Kili ẹnyin mbère lọwọ wọn?
17 Ọkan ninu ijọ enia na si dahùn, wipe, Olukọni, mo mu ọmọ mi ti o ni odi, ẹmi tọ̀ ọ wá;
18 Nibikibi ti o ba gbé si mu u, a si ma nà a tantan: on a si ma yọ ifofó li ẹnu, a si ma pahin keke, a si ma daku; mo si sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ, ki nwọn lé e jade; nwọn ko si le ṣe e.
19 O si da wọn lohùn, o si wipe, Iran alaigbagbọ́ yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? ẹ mu u wá sọdọ mi.
20 Nwọn si mu u wá sọdọ rẹ̀: nigbati o si ri i, lojukanna ẹmi nã nà a tantan; o si ṣubu lulẹ o si nfi ara yilẹ o si nyọ ifofó li ẹnu.
21 O si bi baba rẹ̀ lẽre, wipe, O ti pẹ to ti eyi ti de si i? o si wipe, Lati kekere ni.
22 Nigbakugba ni si ima gbé e sọ sinu iná, ati sinu omi, lati pa a run: ṣugbọn bi iwọ ba le ṣe ohunkohun, ṣãnu fun wa, ki o si ràn wa lọwọ.