33 O si wá si Kapernaumu: nigbati o si wà ninu ile o bi wọn lẽre, wipe, Kili ohun ti ẹnyin mba ara nyin jiyan si li ọ̀na?
34 Ṣugbọn nwọn dakẹ: nitori nwọn ti mba ara wọn jiyan pe, tali ẹniti o pọ̀ju.
35 O si joko, o si pè awọn mejila na, o si wi fun wọn pe, Bi ẹnikẹni ba nfẹ ṣe ẹni iwaju, on na ni yio ṣe ẹni ikẹhin gbogbo wọn, ati iranṣẹ gbogbo wọn.
36 O si mu ọmọ kekere kan, o fi i sarin wọn; nigbati o si gbé e si apa rẹ̀, o wi fun wọn pe,
37 Ẹnikẹni ti o ba gbà ọkan ninu iru awọn ọmọ kekere wọnyi li orukọ mi, o gbà mi: ẹnikẹni ti o ba si gbà mi, ki iṣe emi li o gbà, ṣugbọn o gbà ẹniti o rán mi.
38 Johanu si da a lohùn, o wipe, Olukọni, awa ri ẹnikan nfi orukọ rẹ lé awọn ẹmi èṣu jade, on kò si tọ̀ wa lẹhin: awa si da a lẹkun, nitoriti ko tọ̀ wa lẹhin:
39 Jesu si wipe, Ẹ máṣe da a lẹkun mọ́: nitori kò si ẹnikan ti yio ṣe iṣẹ agbara li orukọ mi, ti o si le yara sọ ibi si mi.