4 Elijah pẹlu Mose si farahàn fun wọn: nwọn si mba Jesu sọ̀rọ.
5 Peteru si dahùn o si wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa lati ma gbé ihinyi: si jẹ ki a pa agọ́ mẹta, ọkan fun ọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah.
6 On kò sá mọ̀ eyi ti iba wi; nitori ẹ̀ru bà wọn gidigidi.
7 Ikuku kan si wá, o ṣiji bò wọn; ohùn kan si ti inu ikuku na wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀.
8 Lojiji, nigbati nwọn si wò yika, nwọn ko si ri ẹnikan mọ́, bikoṣe Jesu nikan pẹlu ara wọn.
9 Bi nwọn si ti nti ori òke sọkalẹ, o paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ ohun ti nwọn ri fun ẹnikan, bikoṣe igbati Ọmọ-enia ba ti jinde kuro ninu okú.
10 Nwọn si fi ọ̀rọ na pamọ́ sinu ara wọn, nwọn si mbi ara wọn lẽre, kili ajinde kuro ninu okú iba jẹ.