10 Emi mbẹ̀bẹ, bi lọna-kọna leke gbogbo rẹ̀, ki a le ṣe ọ̀na mi ni ire nipa ifẹ Ọlọrun, lati tọ̀ nyin wá.
11 Nitoriti emi nfẹ gidigidi lati ri nyin, ki emi ki o le fun nyin li ẹ̀bun ẹmi diẹ, ki a le fi ẹsẹ nyin mulẹ;
12 Eyini ni, ki a le jùmọ ni itunu ninu nyin nipa igbagbọ́ awa mejeji, ti nyin ati ti emi.
13 Ará, emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀ pe, nigba-pupọ li emi npinnu rẹ̀ lati tọ̀ nyin wá (ṣugbọn o di ẹtì fun mi di isisiyi,) ki emi ki o le ni eso diẹ ninu nyin pẹlu, gẹgẹ bi lãrin awọn Keferi iyokù.
14 Mo di ajigbese awọn Hellene ati awọn alaigbede; awọn ọlọ́gbọn ati awọn alaigbọn.
15 Tobẹ̃ bi o ti wà ni ipá mi, mo mura tan lati wasu ihinrere fun ẹnyin ara Romu pẹlu.
16 Nitori emi kò tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu.