Rom 15 YCE

Ẹ Máa Ṣe Ohun Tí Ó Tẹ́ Ẹlòmíràn Lọ́rùn

1 NJẸ o yẹ ki awa ti o lera iba mã ru ẹrù ailera awọn alailera, ki a má si ṣe ohun ti o wù ara wa.

2 Jẹ ki olukuluku wa ki o mã ṣe ohun ti o wù ọmọnikeji rẹ̀ si rere rẹ̀ lati gbe e ró.

3 Nitori Kristi pẹlu kò ṣe ohun ti o wù ara rẹ̀; ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹ̀gan awọn ti ngàn ọ ṣubu lù mi.

4 Nitori ohunkohun ti a ti kọ tẹlẹ, a ti kọ ọ fun kíkọ wa, pe nipa sũru ati itunu iwe-mimọ́ ki a le ni ireti.

5 Njẹ ki Ọlọrun sũru ati itunu ki o fi fun nyin lati ni inu kan si ara nyin gẹgẹ bi Kristi Jesu:

6 Ki ẹnyin ki o le fi ọkàn kan ati ẹnu kan yìn Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa, logo.

Bákan Náà Ni Ìyìn Rere Fún Juu Ati Fún Giriki

7 Nitorina ẹ gbá ara nyin mọra, gẹgẹ bi Kristi ti gbá wa mọra fun ogo Ọlọrun.

8 Mo si wipe, a ti fi Jesu Kristi ṣe iranṣẹ ikọla nitori otitọ Ọlọrun, ki o ba le mu awọn ileri na duro ti a ti ṣe fun awọn baba,

9 Ati ki awọn Keferi ki o le yìn Ọlọrun logo nitori ãnu rẹ̀; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Nitori eyi li emi ó ṣe yin ọ lãrin awọn Keferi, emi o si kọrin si orukọ rẹ.

10 O si tún wipe, Ẹnyin Keferi, ẹ mã yọ̀ pẹlu awọn enia rẹ̀.

11 Ati pẹlu, Ẹ yìn Oluwa gbogbo ẹnyin Keferi; ẹ si kokikí rẹ̀, ẹnyin enia gbogbo.

12 Isaiah si tún wipe, Gbòngbo Jesse kan mbọ̀ wá, ati ẹniti yio dide ṣe akoso awọn Keferi; on li awọn Keferi yio ni ireti si.

13 Njẹ ki Ọlọrun ireti ki o fi gbogbo ayọ̀ on alafia kún nyin ni gbigbagbọ, ki ẹnyin ki o le pọ̀ ni ireti nipa agbara Ẹmí Mimọ́.

Iṣẹ́ Ìyìn Rere Paulu

14 Ará mi, o si da emi tikarami loju nipa ti nyin pe, ẹnyin si kun fun ore, a si fi gbogbo imọ kún nyin, ẹnyin si le mã kìlọ fun ara nyin.

15 Ṣugbọn, ará mi, mo fi igboiya kọwe si nyin li ọna kan, bi ẹni tun nrán nyin leti, nitori ore-ọfẹ ti a ti fifun mi lati ọdọ Ọlọrun wá,

16 Ki emi ki o le ṣe iranṣẹ Jesu Kristi si awọn Keferi, lati ta ọrẹ ihinrere Ọlọrun, ki ọrẹ awọn Keferi ki o le di itẹwọgbà, ti a sọ di mimọ́ nipa Ẹmí Mimọ́.

17 Nitorina mo ni iṣogo ninu Jesu Kristi nipa ohun ti iṣe ti Ọlọrun.

18 Emi kò sá gbọdọ sọ ohun kan ninu eyi ti Kristi kò ti ọwọ́ ṣe, si igbọran awọn Keferi nipa ọ̀rọ ati iṣe,

19 Nipa agbara iṣẹ-àmi ati iṣẹ-iyanu, nipa agbara Ẹmí Ọlọrun; tobẹ̃ lati Jerusalemu ati yiká kiri ani titi fi de Illirikoni, mo ti wasu ihinrere Kristi ni kikun.

20 Mo du u lati mã wasu ihinrere na, kì iṣe nibiti a gbé ti da orukọ Kristi ri, ki emi ki o máṣe mọ amọle lori ipilẹ ẹlomiran.

21 Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Awọn ẹniti a kò ti sọ̀rọ rẹ̀ fun, nwọn ó ri i: ati awọn ti kò ti gbọ́, òye yio yé wọn.

Paulu Ṣe Ètò Láti Lọ Sí Romu

22 Nitorina pẹlu li àye ṣe há fun mi li akoko wọnyi lati tọ̀ nyin wá.

23 Ṣugbọn nisisiyi bi emi kò ti li àye mọ́ li ẹkùn wọnyi, bi emi si ti fẹ gidigidi lati ọdún melo wọnyi lati tọ̀ nyin wá,

24 Nigbakugba ti mo ba nlọ si Spania, ng ó tọ̀ nyin wá: nitori mo nireti pe emi o ri nyin li ọ̀na àjo mi, ati pe ẹ o mu mi já ọ̀na mi nibẹ̀ lati ọdọ nyin lọ, bi mo ba kọ kún fun ẹgbẹ nyin li apakan.

25 Ṣugbọn nisisiyi mo nlọ si Jerusalemu lati ṣe iranṣẹ fun awọn enia mimọ́.

26 Nitoriti o wù awọn ará Makedonia ati Akaia lati da owo jọ fun awọn talakà awọn enia mimọ́ ti o wà ni Jerusalemu.

27 Nitõtọ ifẹ inu rere wọn ni; ajigbese wọn ni nwọn sá ṣe. Nitori bi o ba ṣepe a fi awọn Keferi ṣe alajọni ninu ohun ẹmí wọn, ajigbese si ni wọn lati fi nkan ti ara ta wọn lọrẹ.

28 Nitorina nigbati mo ba ti ṣe eyi tan, ti mo ba si ti dí èdidi eso yi fun wọn tan, emi ó ti ọdọ nyin lọ si Spania.

29 Mo si mọ pe, nigbati mo ba de ọdọ nyin, emi o wá ni kikún ibukún ihinrere Kristi.

30 Mo si bẹ̀ nyin, ará, nitori Oluwa wa Jesu Kristi, ati nitori ifẹ Ẹmí, ki ẹnyin ki o ba mi lakaka ninu adura nyin si Ọlọrun fun mi;

31 Ki a le gbà mi lọwọ awọn alaigbọran ni Judea ati ki iṣẹ-iranṣẹ ti mo ni si Jerusalemu le jẹ itẹwọgbà lọdọ awọn enia mimọ́.

32 Ki emi ki o le fi ayọ̀ tọ̀ nyin wá nipa ifẹ Ọlọrun, ati ki emi le ni itura pọ pẹlu nyin.

33 Njẹ ki Ọlọrun alafia ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16