1 KI olukuluku ọkàn ki o foribalẹ fun awọn alaṣẹ ti o wà ni ipo giga. Nitori kò si aṣẹ kan, bikoṣe lati ọdọ Ọlọrun wá: awọn alaṣẹ ti o si wà, lati ọdọ Ọlọrun li a ti làna rẹ̀ wá.
2 Nitorina ẹniti o ba tapá si aṣẹ, o tapá si ìlana Ọlọrun: awọn ẹniti o ba si ntapá, yio gbà ẹbi fun ara wọn.
3 Nitori awọn ijoye kì iṣe ẹ̀ru si iṣẹ rere, bikoṣe si iṣẹ buburu. Njẹ iwọ ha fẹ ṣaibẹru aṣẹ wọn? ṣe eyi ti o dara, iwọ ó si gbà iyìn lati ọdọ rẹ̀:
4 Nitori iranṣẹ Ọlọrun ni iṣe si ọ fun rere. Ṣugbọn bi iwọ ba nṣe buburu, bẹru; nitori kò gbé idà na lasan: nitori iranṣẹ Ọlọrun ni iṣe, olugbẹsan lati ṣiṣẹ ibinu lara ẹniti nṣe buburu.
5 Nitorina ẹnyin kò gbọdọ ṣaima tẹriba, kì iṣe nitoriti ibinu nikan, ṣugbọn nitori ẹri-ọkàn pẹlu.
6 Nitori idi eyi na li ẹ ṣe san owo-ode pẹlu: nitori iranṣẹ Ọlọrun ni nwọn eyiyi na ni nwọn mbojuto nigbagbogbo.
7 Nitorina ẹ san ohun ti o tọ fun ẹni gbogbo: owo-ode fun ẹniti owo-ode iṣe tirẹ̀: owo-bode fun ẹniti owo-bode iṣe tirẹ̀; ẹ̀ru fun ẹniti ẹ̀ru iṣe tirẹ̀; ọlá fun ẹniti ọlá iṣe tirẹ̀.
8 Ẹ máṣe jẹ ẹnikẹni ni gbese ohun kan, bikoṣepe ki a fẹran ọmọnikeji ẹni: nitori ẹniti o ba fẹran ọmọnikeji rẹ̀, o kó ofin já.
9 Nitori eyi, Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga, Iwọ kò gbọdọ pania, Iwọ kò gbọdọ jale, Iwọ kò gbọdọ jẹri eke, Iwọ kò gbọdọ ṣojukòkoro; bi ofin miran ba si wà, a ko o pọ ninu ọ̀rọ yi pe, Fẹran ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.
10 Ifẹ kì iṣe ohun buburu si ọmọnikeji rẹ̀: nitorina ifẹ li akója ofin.
11 Ati eyi, bi ẹ ti mọ̀ akokò pe, o ti to wakati nisisiyi fun nyin lati ji loju orun: nitori nisisiyi ni igbala wa sunmọ etile jù igbati awa ti gbagbọ́ lọ.
12 Oru bukọja tan, ilẹ si fẹrẹ mọ́: nitorina ẹ jẹ ki a bọ́ ara iṣẹ òkunkun silẹ, ki a si gbe ihamọra imọlẹ wọ̀.
13 Jẹ ki a mã rìn ìrin titọ, bi li ọsán; kì iṣe ni iréde-oru ati ni imutipara, kì iṣe ni iwa-ẽri ati wọbia, kì iṣe ni ìja ati ilara.
14 Ṣugbọn ẹ gbe Jesu Kristi Oluwa wọ̀, ki ẹ má si pèse fun ara, lati mã mu ifẹkufẹ rẹ̀ ṣẹ.