1 ṢUGBỌN ẹniti o ba ṣe ailera ni igbagbọ́ ẹ gbà a, li aitọpinpin iṣiyemeji rẹ̀.
2 Ẹnikan gbagbọ́ pe on le mã jẹ ohun gbogbo: ẹlomiran ti o si ṣe alailera njẹ ewebẹ.
3 Ki ẹniti njẹ máṣe kẹgan ẹniti kò jẹ; ki ẹniti kò si jẹ ki o máṣe dá ẹniti njẹ lẹjọ: nitori Ọlọrun ti gbà a.
4 Tani iwọ ti ndá ọmọ-ọdọ ẹlomĩ lẹjọ? loju oluwa rẹ̀ li o duro, tabi ti o ṣubu. Nitotọ a o si mu u duro: nitori Oluwa ni agbara lati mu u duro.
5 Ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ kan jù omiran lọ: ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ gbogbo bakanna. Ki olukuluku ki o da ara rẹ̀ loju ni inu ara rẹ̀.
6 Ẹniti o ba nkiyesi ọjọ, o nkiyesi i fun Oluwa; ẹniti kò ba si kiyesi ọjọ, fun Oluwa ni kò kiyesi i. Ẹniti njẹun, o njẹun fun Oluwa, nitori o ndupẹ lọwọ Ọlọrun; ẹniti kò ba si jẹun, fun Oluwa ni kò jẹun, o si ndupẹ lọwọ Ọlọrun.
7 Nitori kò si ẹnikan ninu wa ti o wà lãye fun ara rẹ̀, kò si si ẹniti o nkú fun ara rẹ̀.
8 Nitori bi a ba wà lãye, awa wà lãye fun Oluwa; bi a ba si kú, awa kú fun Oluwa: nitorina bi a wà lãye, tabi bi a kú ni, ti Oluwa li awa iṣe.
9 Nitori idi eyi na ni Kristi ṣe kú, ti o si tún yè, ki o le jẹ Oluwa ati okú ati alãye.
10 Ṣugbọn ẽṣe ti iwọ fi nda arakunrin rẹ lẹjọ? tabi ẽsitiṣe ti iwọ fi nkẹgan arakunrin rẹ? gbogbo wa ni yio sá duro niwaju itẹ́ idajọ Kristi.
11 Nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wipe, Bi emi ti wà, gbogbo ẽkún ni yio kunlẹ fun mi, ati gbogbo ahọn ni yio si jẹwọ fun Ọlọrun.
12 Njẹ nitorina, olukuluku wa ni yio jihin ara rẹ̀ fun Ọlọrun.
13 Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a tun mã da ara wa lẹjọ mọ́: ṣugbọn ẹ kuku mã ṣe idajọ eyi, ki ẹnikẹni máṣe fi ohun ikọsẹ tabi ohun idugbolu si ọ̀na arakunrin rẹ̀.
14 Mo mọ̀, o si dá mi loju ninu Jesu Oluwa pe, kò si ohun ti o ṣe aimọ́ fun ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba kà ohunkohun si aimọ́, on li o ṣe aimọ́ fun.
15 Ṣugbọn bi inu arakunrin rẹ ba bajẹ nitori onjẹ rẹ, njẹ iwọ kò rìn ninu ifẹ mọ́. Ẹniti Kristi kú fun, máṣe fi onjẹ rẹ pa a kúgbe.
16 Njẹ ẹ máṣe jẹ ki a mã sọ̀rọ ire nyin ni buburu.
17 Nitori ijọba Ọlọrun kì iṣe jijẹ ati mimu; bikoṣe ododo, ati alafia, ati ayọ̀ ninu Ẹmí Mimọ́.
18 Nitori ẹniti o ba nsìn Kristi ninu nkan wọnyi, li o ṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun, ti o si ni iyin lọdọ enia.
19 Njẹ nitorina, ki awa ki o mã lepa ohun ti iṣe ti alafia, ati ohun ti awa o fi gbe ara wa ró.
20 Nitori onjẹ máṣe bi iṣẹ Ọlọrun ṣubu. Ohun gbogbo li o mọ́ nitõtọ; ṣugbọn ibi ni fun oluwarẹ̀ na ti o njẹun lọna ikọsẹ.
21 O dara ki a má tilẹ jẹ ẹran, ki a má mu waini, ati ohun kan nipa eyi ti arakunrin rẹ yio kọsẹ, ati ti a o si fi sọ ọ di alailera.
22 Iwọ ní igbagbọ́ bi? ní i fun ara rẹ niwaju Ọlọrun. Alabukun-fun ni oluwarẹ̀ na ti ko da ara rẹ̀ lẹbi ninu ohun ti o yàn.
23 Ṣugbọn ẹniti o ba nṣiyemeji, o jẹbi bi o ba jẹ, nitoriti kò ti inu igbagbọ́ wá: ati ohunkohun ti kò ti inu igbagbọ wá, ẹṣẹ ni.