2 Ẹnikan gbagbọ́ pe on le mã jẹ ohun gbogbo: ẹlomiran ti o si ṣe alailera njẹ ewebẹ.
3 Ki ẹniti njẹ máṣe kẹgan ẹniti kò jẹ; ki ẹniti kò si jẹ ki o máṣe dá ẹniti njẹ lẹjọ: nitori Ọlọrun ti gbà a.
4 Tani iwọ ti ndá ọmọ-ọdọ ẹlomĩ lẹjọ? loju oluwa rẹ̀ li o duro, tabi ti o ṣubu. Nitotọ a o si mu u duro: nitori Oluwa ni agbara lati mu u duro.
5 Ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ kan jù omiran lọ: ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ gbogbo bakanna. Ki olukuluku ki o da ara rẹ̀ loju ni inu ara rẹ̀.
6 Ẹniti o ba nkiyesi ọjọ, o nkiyesi i fun Oluwa; ẹniti kò ba si kiyesi ọjọ, fun Oluwa ni kò kiyesi i. Ẹniti njẹun, o njẹun fun Oluwa, nitori o ndupẹ lọwọ Ọlọrun; ẹniti kò ba si jẹun, fun Oluwa ni kò jẹun, o si ndupẹ lọwọ Ọlọrun.
7 Nitori kò si ẹnikan ninu wa ti o wà lãye fun ara rẹ̀, kò si si ẹniti o nkú fun ara rẹ̀.
8 Nitori bi a ba wà lãye, awa wà lãye fun Oluwa; bi a ba si kú, awa kú fun Oluwa: nitorina bi a wà lãye, tabi bi a kú ni, ti Oluwa li awa iṣe.