14 Nitori ẹ̀ṣẹ kì yio ni ipa lori nyin: nitori ẹnyin kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ.
15 Njẹ kini? ki awa ki o ha ma dẹṣẹ̀, nitoriti awa kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ? Ki a má ri.
16 Ẹnyin kò mọ̀ pe, ẹniti ẹnyin ba jọwọ ara nyin lọwọ fun bi ẹrú lati mã gbọ́ tirẹ̀, ẹrú ẹniti ẹnyin ba gbọ tirẹ̀ li ẹnyin iṣe; ibãṣe ti ẹ̀ṣẹ sinu ikú, tabi ti igbọran si ododo?
17 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun pe, bi ẹnyin ti jẹ ẹrú ẹ̀ṣẹ rí, ẹnyin jẹ olugbọran lati ọkàn wá si apẹrẹ ẹkọ ti a fi nyin le lọwọ.
18 Bi a si ti sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ẹnyin di ẹrú ododo.
19 Emi nsọ̀rọ bi enia nitori ailera ara nyin: nitori bi ẹnyin ti jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ bi ẹrú fun iwa-ẽri ati fun ẹ̀ṣẹ de inu ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ gẹgẹ ni ki ẹnyin ki o jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ nisisiyi bi ẹrú fun ododo si ìwa-mimọ́.
20 Nitori nigbati ẹnyin ti jẹ ẹrú ẹ̀ṣẹ, ẹnyin wà li omnira si ododo.