7 Nitori ẹniti o kú, o bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ.
8 Ṣugbọn bi awa ba bá Kristi kú, awa gbagbọ́ pe awa ó si wà lãye pẹlu rẹ̀:
9 Nitori awa mọ̀ pé bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú, kò ni ikú mọ́; ikú kò ni ipa lori rẹ̀ mọ́.
10 Nitori iku ti o kú, o kú si ẹ̀ṣẹ lẹ̃kan: nitori wiwà ti o wà lãye, o wà lãye si Ọlọrun.
11 Bẹ̃ni ki ẹnyin pẹlu kà ara nyin bi okú si ẹ̀ṣẹ, ṣugbọn bi alãye si Ọlọrun ninu Kristi Jesu.
12 Nitorina ẹ maṣe jẹ ki ẹ̀ṣẹ ki o jọba ninu ara kiku nyin, ti ẹ o fi mã gbọ ti ifẹkufẹ rẹ̀;
13 Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ fun ẹ̀ṣẹ bi ohun elo aiṣododo; ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Ọlọrun, bi alãye kuro ninu okú, ati awọn ẹ̀ya ara nyin bi ohun elo ododo fun Ọlọrun.