1 NJẸ ẹbi kò si nisisiyi fun awọn ti o wà ninu Kristi Jesu, awọn ti kò rìn nipa ti ara, bikoṣe nipa ti Ẹmí.
2 Nitori ofin Ẹmí ìye ninu Kristi Jesu ti sọ mi di omnira lọwọ ofin ẹ̀ṣẹ ati ti ikú.
3 Nitori ohun ti ofin kò le ṣe, bi o ti jẹ alailera nitori ara, Ọlọrun rán Ọmọ on tikararẹ̀ li aworan ara ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, o si da ẹ̀ṣẹ lẹbi ninu ara:
4 Ki a le mu ododo ofin ṣẹ ninu awa, ti kò rin nipa ti ara, bikoṣe nipa ti Ẹmí.
5 Nitori awọn ti o wà nipa ti ara, nwọn a mã ro ohun ti ara; ṣugbọn awọn ti o wà nipa ti Ẹmí, nwọn a mã ro ohun ti Ẹmí.
6 Nitori ero ti ara ikú ni; ṣugbọn ero ti Ẹmí ni iye ati alafia: