20 Bẹ̃kọ, iwọ enia, tani iwọ ti nda Ọlọrun lohùn? Ohun ti a mọ a ha mã wi fun ẹniti ti o mọ ọ pé, Ẽṣe ti iwọ fi mọ mi bayi?
21 Amọ̀koko kò ha li agbara lori amọ̀, ninu ìṣu kanna lati ṣe apakan li ohun elo si ọlá, ati apakan li ohun elo si ailọlá?
22 Njẹ bi Ọlọrun ba fẹ fi ibinu rẹ̀ hàn nkọ, ti o si fẹ sọ agbara rẹ̀ di mimọ̀, ti o si mu suru pupọ fun awọn ohun elo ibinu ti a ṣe fun iparun;
23 Ati ki o le sọ ọrọ̀ ogo rẹ̀ di mimọ̀ lara awọn ohun elo ãnu ti o ti pèse ṣaju fun ogo,
24 Ani awa, ti o ti pè, kì iṣe ninu awọn Ju nikan, ṣugbọn ninu awọn Keferi pẹlu?
25 Bi o ti wi pẹlu ni Hosea pe, Emi ó pè awọn ti kì iṣe enia mi, li enia mi, ati ẹniti ki iṣe ayanfẹ li ayanfẹ.
26 Yio si ṣe, ni ibi ti a gbé ti sọ fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, nibẹ̀ li a o gbé pè wọn li ọmọ Ọlọrun alãye.