Dáníẹ́lì 11:23-29 BMY

23 Lẹ́yìn tí ó wá ṣe ìpinnu pẹ̀lú u rẹ̀, yóò hùwà ẹ̀tàn, pẹ̀lú iwọ̀nba ènìyàn kékeré ni yóò gba ìjọba.

24 Nígbà tí àwọn agbègbè tí ó lọ́rọ̀ gidigidi wà láìbẹ̀rù ni yóò gbógun tì wọ́n, yóò ṣe ohun tí baba rẹ̀ tàbí baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí, yóò pín ìkógún ẹrù àti ọrọ̀ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn in rẹ̀. Yóò pète àti bi àwọn ìlú olódi ṣubú, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀ ni.

25 “Pẹ̀lú ogun púpọ̀, yóò sì ru agbára rẹ̀ àti ìgboyà rẹ̀ ṣókè sí ọba Gúṣù. Ọba Gúṣù yóò dìde ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun tí ó lágbára gidigidi, ṣùgbọ́n kò ní leè dúró, nítorí ọ̀tẹ̀ tí ó gbérò sí i.

26 Àwọn tí ó jẹ nínú oúnjẹ ọba yóò gbìyànjú láti parun: a ó gbá ogun rẹ̀ dànú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò ṣubú sí ogun.

27 Àwọn ọba méjèèjì, ọkàn wọn tẹ̀ sí búburú, wọn yóò jókòó lórí tábìlì kan, wọn yóò máa parọ́ sí ara wọn, ṣùgbọ́n kò ní yọrí sí nǹkan kan nítorí òpin yóò wá ní àsìkò tí a yàn.

28 Ọba àríwá yóò padà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ yóò lòdì sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì ṣiṣẹ́ lòdì sí i, yóò sì padà sí orílẹ̀-èdè oun fúnra rẹ̀.

29 “Ní àsìkò tí a yàn, yóò gbógun sí Gúṣù lẹ́ẹ̀ kan sí i, ṣùgbọ́n ní ìgbà yí àyọrísí yóò yàtọ̀ sí ti ìṣáájú.