1 Nígbà tí ó di ọdún kẹta ìjọba Beliṣáṣárì ọba, èmi Dáníẹ́lì rí ìran kan èyí tí mo ti rí tẹ́lẹ̀.
2 Nínú ìran náà, mo rí ara mi nínú ilé ìṣọ́ ní Súsáni ní agbègbè ìjọba Élámù: nínú ìran náà mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Úláì.
3 Mo wo òkè mo sì rí àgbò kan tí ó ní ìwo méjì níwájú ù mi, ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Úláì, àwọn ìwo méjèèje sì gùn. Ṣùgbọ́n ọ̀kan gùn ju èkejì lọ, èyí tí ó gùn jù ni ó yọ jáde kẹ́yìn.
4 Mo rí àgbò náà ó ń kàn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, sí àríwá, àti sí gúsù, kò sí ẹranko kankan tí ó leè dojú kọọ́, kò sí ẹnìkan tí ó leè yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀, ó ń ṣe bí ó ti wù ú, ó sì di alágbára.
5 Bí mo ṣe ń ronú nípa èyí, lójijì ni òbúkọ kan tí ó ní ìwo láàrin ojú u rẹ̀ méjèèjì jáde láti ìhà ìwọ̀ oòrùn, ó la gbogbo ayé kọjá láì fi ara kan ilẹ̀.
6 Ó tọ àgbò tí ó ni ìwo méjì náà wá, èyí tí mo rí tó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Úláì, ó sì dojú kọ ọ́ pẹ̀lú ìrunú tí ó lágbára.
7 Mo ríi tí ó fi ìtara kọlu àgbò náà, ó lu àgbò náà bolẹ̀, ó sì ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì. Àgbò náà kò sì ní agbára láti dojú kọ ọ́, Òbúkọ náà kàn-án mọ́lẹ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀, kò sì sí ẹni tí ó lè gba àgbò náà là kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.
8 Òbúkọ náà sì di alágbára púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé góńgó, agbára rẹ̀ ru sókè, ìwo ńlá a rẹ̀ sì ṣẹ́ dànù, ní ipò o rẹ̀, ìwo mẹ́rin mìíràn hù, ó sì yọrí sí ìhà igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.
9 Lára ọ̀kan nínú un wọn, ìwo mìíràn yọ jáde, ó kékeré, ṣùgbọ́n ó dàgbà nínú agbára sí ìhà gúsù, àti sí ìhà ìlà oòrun àti sí ilẹ̀ dídára.
10 Ó sì dàgbà títí ó fi kan ẹgbẹ́ ogun ọ̀run, ó sì jù lára àwọn ẹgbẹ́ ogun ọ̀run sí ayé ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀,
11 ó sì gbé ara rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí ọmọ aládé ẹgbẹ́ ogun ọ̀run; ó sì mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò lọ́dọ̀ ọ rẹ̀, ó sì gba àyè ibi mímọ́ rẹ̀.
12 A fún-un ní ẹgbẹ́ ogun ọ̀run àti ẹbọ ojojúmọ́ nítorí ìwà ọlọ̀tẹ̀ ẹ rẹ̀: ó sọ òtítọ́ nù nínú gbogbo ohun tó ṣe.
13 Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ ń sọ̀rọ̀, àti ẹni mímọ́ mìíràn sọ̀rọ̀ fún-un pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ìran yìí yóò fi wá sí ìmúsẹ-ìran nípa ẹbọ ojojúmọ́, ìṣọ̀tẹ̀ tí ó ń sọ dahoro, àti mímú kí ibi mímọ́ àti ẹgbẹ́ ogun ọ̀run di ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”
14 Ó sọ fún mi pé, “Yóò gbà tó ẹgbọ̀kànlá lé lọ́gọ́rùn-ún (2,300) alẹ́ àti òwúrọ̀; lẹ́yìn náà ni a ó tún ibi mímọ́ yà sí mímọ́.”
15 Nígbà tí èmi Dáníẹ́lì, ń wo ìran náà, mo sì ń fẹ́ kí ó yé mi, ẹnìkan tí ó sì dúró níwájú ù mi.
16 Mo gbọ́ ohùn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ Úláì, tí ó ń pè pẹ́ “Gébúrẹ́lì, sọ ìtumọ̀ ìran náà fún ọkùnrin yìí.”
17 Bí ó ṣe súnmọ́ ibi tí mo dúró sí, ẹ̀rù bàmí, mo sì dọ̀bálẹ̀. Ó ń sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ́ kí ó yé ọ pé ìran náà ń sọ nípa ìgbà ìkẹyìn ni.”
18 Bí ó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo ti sùn lọ fọnfọn, bí mo ṣe da ojú bolẹ̀. Nígbà náà ni ó fi ọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi.
19 Ó sọ wí pé: “Èmi yóò sọ ohun tí yóò sẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ní ìgbà ìbínú, nítorí ìran náà jẹ mọ́ àkókò ohun tí a yàn nígbà ìkẹyìn.
20 Àgbò oníwo méjì tí o rí, òun ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba Médíánì àti Páṣíà.
21 Òbúkọ onírun náà ni ọba Gíríkì, ìwo ńlá ti ó wà láàrin ojú u rẹ̀ ni ọba àkọ́kọ́.
22 Ìwo mẹ́rin ti ó dípo ọ̀kan tí ó kán dúró, èyí dúró gẹ́gẹ́ bí ìjọba mẹ́rin tí ó dìde láti orílẹ̀ èdè e rẹ̀ ṣùgbọ́n wọn kò ní ní irú agbára kan náà.
23 “Ní ìgbà ìkẹyìn ìjọba wọn, nígbà tí ìwà búburú àwọn ọlọ̀tẹ̀ bá burú gidigidi ọba tí ojú u rẹ̀ le koko, balógun rìkísí yóò dìde.
24 Yóò di alágbára, ṣùgbọn tí kì í ṣe nípa agbára rẹ̀. Yóò sì máa ṣe ìparun tí yóò ya ni lẹ́nu, yóò sì máa ṣe àṣeyọri nínú ohun gbogbo tó ń ṣe. Yóò sì run àwọn alágbára àti àwọn ènìyàn mímọ́.
25 Nípa àrékérekè rẹ̀, yóò mú kí ẹ̀tàn gbèrú, yóò gbé ara rẹ̀ ga nínú ọkàn rẹ̀, nígbà tí wọ́n rò wí pé àlàáfíà dé, yóò sì pa àwọn ènìyàn run, nígbà tí wọn kò rò tẹ́lẹ̀, yóò sì lòdì sí olórí àwọn ọmọ aládé, ṣíbẹ̀, a ó paárun ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa agbára ènìyàn.
26 “Ìran alẹ́ àti ti òwúrọ̀, tí a fi hàn ọ́ jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n pa ìran náà mọ́, nítorí pé, ó jẹ mọ́ ti ọjọ́ iwájú”
27 Èmi Dáníẹ́lì sì ṣe àárẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan. Nígbà náà, mo dìde, mo sì ń bá isẹ́ ọba lọ. Ìran náà sì bàmí lẹ́rù, kò sì yé mi.