1 Nebukadinéṣárì ọba gbẹ́ ère wúrà kan, èyí tí gíga rẹ̀ tó àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ tó ẹsẹ̀ mẹ́fà, ó sì gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà ní agbègbè ìjọba Bábílónì.
2 Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ aládé, àwọn olóyè, àwọn ìgbìmọ̀, àwọn baálẹ̀, àwọn balógun, àwọn onídàájọ́, àwọn olùtọ́jú ìṣúra àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba láti wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀.
3 Nígbà náà ni àwọn ọmọ aládé, àwọn olóyè, àwọn onímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba, wọn péjọ láti ya ère tí Nebukadinésárì ọba gbé kalẹ̀ sí mímọ́, gbogbo wọn sì dúró síwájú u rẹ̀.
4 Nígbà náà ni a kéde kígbe sókè wí pé, “Ohun tí a paláṣẹ fún un yín láti ṣe nìyìí, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè àti èdè gbogbo:
5 Bí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò, kí ẹ wólẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀.
6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ tí kò bá wólẹ̀, kí ó fi orí balẹ̀, kí a ju ẹni náà sínú iná ìléru.”
7 Nítorí náà, bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè, àti èdè gbogbo wólẹ̀, wọ́n sì fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadinéṣárì gbé kalẹ̀.
8 Ní àsìkò yìí ni àwọn awòràwọ̀ bọ́ síwájú, wọ́n sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ará a Júdà.
9 Wọ́n sọ fún ọba Nebukadinṣárì pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.
10 Ìwọ ọba ti pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin gbọdọ̀ wólẹ̀ kí ó fi orí balẹ̀ fún ère wúrà
11 àti ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó forí balẹ̀, a ó sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú iná ìléru.
12 Ṣùgbọ́n àwọn ará a Júdà kan wà, àwọn tí a yàn láti ṣe olórí agèégbè ìjọba Bábílónì: Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, wọ́n ò ka ìwọ ọba sí. Wọn kò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”
13 Nígbà náà ni Nebukadinéṣárì pàṣẹ ní ìrunú àti ìbínú pé kí a mú Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò wá, wọ́n sì mú wọn wá síwájú ọba.
14 Nebukadinéṣárì wí fún wọn wí pé, “Ṣé òtítọ́ ni, Sádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò wí pé ẹ̀yin kò sin òrìṣà mi àti pé ẹ̀yin kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí èmi gbé kalẹ̀.
15 Ní ìsinsìnyìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókun, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetan láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru. Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”
16 Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò dá ọba lóhùn wí pé, “Nebukadinéṣárì, kì í ṣe fún wa láti gba ara wa sílẹ̀ níwájú u rẹ nítorí ọ̀rọ̀ yìí.
17 Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú un rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba.
18 Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ dájú wí pé àwa kò ní sin òrìṣà rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”
19 Nígbà náà ni Nebukadinéṣárì bínú gidigidi sí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, ojú u rẹ̀ sì yípadà, ó sì pàṣẹ pé, kí wọn dá iná ìléru náà kí ó gbóná ní ìlọ́po méje ju èyí tí wọn ń dá tẹ́lẹ̀,
20 ó sì pàṣẹ fún àwọn alágbára nínú ogun rẹ̀ pé, kí wọ́n de Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, kí wọn sì jù wọ́n sínú iná ìléru.
21 Nígbà náà ni a dè wọ́n pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn, ṣòkòtò, ìbòrí àti àwọn aṣọ mìíràn, a sì jù wọ́n sínú iná ìléru.
22 Nítorí bí àsẹ ọba ṣe le tó, tí iná ìléru náà sì gbóná, ọwọ́ iná pa àwọn ọmọ ogun tí wọ́n mú Sádírákì, Mésákì àti Àbẹ́dinígò lọ.
23 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò ṣubú lulẹ̀ sínú iná ìléru náà pẹ̀lú bí a ṣe dè wọ́n.
24 Nígbà náà ni ó ya Nebukadinéṣárì ọba lẹ́nu, ó sì yára dìde dúró, ó bèèrè lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ pé, “Ṣe bí àwọn mẹ́ta ni a gbé jù sínú iná?”Wọ́n wí pé, “Òtítọ́ ni ọba.”
25 Ó sì wí pé, “Wò ó! Mo rí àwọn mẹ́rin tí a kò dè tí wọ́n ń rìn ká nínú iná, ẹnì kẹrin dàbí ọmọ Ọlọ́run.”
26 Nígbà náà, ni Nebukadinésárì dé ẹnu ọ̀nà iná ìléru, ó sì kígbe pé, “Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀gá ògo, ẹ jáde, ẹ wá níbi!”Nígbà náà ni Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò jáde láti inú iná.
27 Àwọn ọmọ aládé, ìjòyè, baálẹ̀, àwọn ìgbìmọ̀ ọba pé jọ sí ọ̀dọ̀ ọ wọn. Wọ́n rí i wí pé iná kò ní agbára lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò jó wọn lára, bẹ́ẹ̀ ni irun orí i wọn kò jóná, àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn kò jóná, òórùn iná kò rùn ní ara wọn rárá.
28 Nígbà náà, ni Nebukadinésárì sọ wí pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, ẹni tí ó rán ańgẹ́lì rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àsẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí forí balẹ̀ fún Ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn.
29 Nítorí náà, mo pa àṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, orílẹ̀ èdè tàbí èdè kan tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò kí a gé wọn sí wẹ́wẹ́ kí a sì sọ ilé e wọn di ààtàn; nítorí kò sí Ọlọ́run mìíràn tí ó lè gba ènìyàn bí irú èyí.”
30 Nígbà náà ni ọba gbé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò ga ní gbogbo agbégbé ìjọba Bábílónì.