Dáníẹ́lì 2 BMY

Àlá Nebukadinéṣárì

1 Ní ọdún kejì ìjọba Nebukadinéṣárì, ó lá àlá, èyí tí ó mú kí ọkàn an rẹ̀ dàrú, kò sì le è sùn.

2 Nígbà náà ni ọba yára pe àwọn onídán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn oṣó àti àwọn awòràwọ̀; àwọn tó ní ìmọ̀ àti àsírí i títúmọ̀ ìràwọ̀, ọba pè wọ́n kí wọn wá sọ àlá tí ó lá. Nígbà tí wọ́n dé, tí wọ́n dúró níwájú ọba,

3 ó sọ fún wọn pé, “Mo ti lá àlá kan èyí tí ó mú kí ọkàn mi dàrú, mo sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ àlá náà.”

4 Nígbà náà ni àwọn awòràwọ̀ dá ọba lóhùn ní èdè Árámáíkì pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Sọ àlá yìí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ àwa yóò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”

5 Ọba dá àwọn awòràwọ̀ lóhùn pé, “Ohun náà ti kúrò lórí mi: tí ẹ̀yin kò bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò gé e yín sí wẹ́wẹ́, ilé e yín yóò sì di ààtàn.

6 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò fún un yín ní ẹ̀bùn, ọrẹ àti ọláńlá tí ó pọ̀. Nítorí náà, ẹ sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.”

7 Lẹ́ẹ̀kan sí i, “Wọ́n tún dáhùn pé, jẹ́ kí ọba sọ àlá náà fún ìránṣẹ́ rẹ̀, àwa yóò sì túmọ̀ rẹ̀.”

8 Nígbà náà ni ọba sọ pé, “Èmi mọ̀ dájú wí pé ẹ̀yin fẹ́ fi àkókò ṣòfò nítorí pé ẹ̀yin ti mọ̀ pé nǹkan ti lọ ní orí mi:

9 Tí ẹ̀yin kò bá lè sọ àlá mi, ìjìyà kan ṣoṣo ló wà fún un yín. Ẹ̀yin ti gbèrò láti pa irọ́ àti láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ti ó lè ṣi ni lọ́nà fún mi, títí tí nǹkan yóò fi yí wọ́. Nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, èmi yóò sì mọ̀ pé ẹ lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”

10 Àwọn awòràwọ̀ sì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ènìyàn kan ní ayé tí ó lè sọ nǹkan tí ọba béèrè! Kò sí ọba náà bí ó ti wù kí ó tóbi àti kí ó lágbára tó, tí í béèrè irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tàbí awòràwọ̀.

11 Nǹkan tí ọba béèrè yìí ṣòro púpọ̀. Kò sí ẹni tí ó lè fi han ọba à fi àwọn òrìṣà, tí wọn kì í gbé láàrin ènìyàn.”

12 Èyí mú kí ọba bínú, ó sì kanra, nítorí náà ó pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn amòye Bábílónì run.

13 Nítorí náà àṣẹ yìí jáde lọ wí pé kí a pa àwọn amòye, wọ́n ránṣẹ́ pe Dáníẹ́lì pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti pa wọ́n.

14 Nígbà tí Áríókù, olórí àwọn olùṣọ́ ọba, jáde láti lọ pa àwọn amòye Bábílónì, Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ fún un pẹ̀lú ọgbọ́n àti òye.

15 Ó béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùṣọ́ ọba wí pé, “Èéṣe tí àṣẹ ọba fi yá kánkán bẹ́ẹ̀?” Áríókù sì ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Dáníẹ́lì.

16 Nígbà náà ni Dáníẹ́lì wọlé tọ ọba lọ, ó sì tọrọ kí ọba fún òun ní ààyè, òun yóò fi ìtumọ̀ àlá náà hàn fún ọba.

17 Nígbà náà ni Dáníẹ́lì padà lọ sí ilé e rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Hananíáyà, Míṣáẹ́lì àti Ásáríyà.

18 Ó sọ fún wọn pé kí wọn bèèrè fún àánú Ọlọ́run ọ̀run nípa àsírí náà, kí ọba má ba à pa àwọn run pẹ̀lú àwọn amòye Bábílónì.

19 Ní òru, àsírí náà hàn sí Dáníẹ́lì ní ojú ìran. Nígbà náà ni Dáníẹ́lì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run

20 Dáníẹ́lì wí pé:“Ọpẹ́ ni fún orúkọ Olúwa láé àti láéláé;tirẹ̀ ni ọgbọ́n àti agbára

21 Ó yí ìgbà àti àkókò padà;ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò.Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́nàti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.

22 Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àsírí hàn;ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùnàti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà

23 Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi:ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbáraó ti fi àwọn nǹkan tí a bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún minítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”

Dáníẹ́lì Túmọ̀ Àlá

24 Nígbà náà ni Dáníẹ́lì títọ́ Áríókù lọ, ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn amòye Bábílónì run, Dáníẹ́lì wí fún un pé, “Má ṣe pa àwọn amòye Bábílónì run. Mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, èmi yóò sí sọ ìtumọ̀ àlá rẹ̀ fún un.”

25 Lẹ́ṣẹ̀kan náà, Áríókù yára mú Dáníẹ́lì lọ sí iwájú ọba, ó sọ fún ọba pé, “Èmi ti rí ọkùnrin kan lára àwọn àjèjì tí ó wá láti Júdà, ẹni tí ó lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.”

26 Ọba béèrè lọ́wọ́ ọ Dáníẹ́lì ẹni tí a tún ń pè ní Beliteṣáṣárì pé, “Ṣé ìwọ lè sọ ohun tí mo rí nínú àlá mi àti ìtumọ̀ ọ rẹ̀ fún mi?”

27 Dáníẹ́lì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àsírí tí ọba béèrè fún

28 ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àsírí hàn. Ó ti fi han ọba Nebukadinéṣárì, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí:

29 “Ọba, bí ìwọ ṣe ṣùn sórí ibùsùn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ ń ro àwọn ohun tó ń bọ̀, olùfihàn àsírí ń fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún ọ.

30 Ṣùgbn fún èmi, a fi àsírí yìí hàn mí, kì í ṣe pé mo ní ọgbọ́n tí ó pọ̀ ju ti alààyè kankan lọ, ṣùgbọ́n nítorí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá àti kí ó lè mọ ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ̀.

31 “Ìwọ ọba ń wo, ère ńlá kan tí ó dúró níwájú ù rẹ, ère náà ga, ó sì dára láti wò, ìrísí i rẹ̀ ba ni lẹ́rù jọjọ.

32 Orí ère náà jẹ́ kìkì wúrà, àyà rẹ̀ àti ọwọ́ ọ rẹ̀ jẹ́ fàdákà, inú àti ẹ̀gbẹ́ itan rẹ̀ jẹ́ idẹ,

33 àwọn ẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ́ irin, àwọn àtẹ́lẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ́ apákan irin àti apákan amọ̀.

34 Bí ó ṣe ń wò, òkúta kan wá, tí kò wá láti ọwọ́ ẹnìkankan. Ó kọlu ère náà ní àtẹ́lẹṣẹ̀ irin àti amọ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́ẹ́wẹ́.

35 Nígbà náà ni irin, amọ̀, idẹ, fàdákà àti wúrà fọ́ sí wẹ́wẹ́ lẹ́ṣẹ̀ kan náà, ó sì dàbí ìyàngbò tí a fẹ́ kúrò lórí ọkà ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Afẹ́fẹ́ gbé gbogbo rẹ̀ lọ láì ṣẹ́ku ọ̀kan mọ́, òkúta tí ó fọ́ ère náà sì di òkè ńlá, ó sì gba gbogbo ayé.

36 “Èyí ni àlá náà, nígbà yìí ni a ó wá sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.

37 Ìwọ ọba jẹ́ ọba àwọn ọba. Ọlọ́run ọ̀run ti fi ìjọba agbára, títóbi àti ògo fún ọ;

38 ní ọwọ́ rẹ ló fi gbogbo ènìyàn, àwọn ẹranko ìgbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run sí. Ní ibi gbogbo tí wọ́n ń gbé, ó ti fi ọ́ ṣe olórí i wọn. Ìwọ ni orí i wúrà náà.

39 “Lẹ́yìn èyí ni ìjọba mìíràn yóò dìde, tí kò ní lágbára tó tìrẹ, lẹ́yìn in rẹ̀, ìjọba kẹta tí yóò dàbí idẹ, èyí tí yóò jọba lórí i gbogbo ayé.

40 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìjọba kẹrin yóò wà, ìjọba náà yóò lágbára bí irin, gẹ́gẹ́ bí irin ti í fọ́, tó sì ń lọ gbogbo nǹkan àti bí irin ti í fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́, bẹ́ẹ̀ ni yóò fọ́ tí yóò sì lọ gbogbo àwọn tó kù.

41 Bí o ṣe rí i tí àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹṣẹ̀ jẹ́ apákan amọ̀ àti apákan irin, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yóò ṣe pín; ṣùgbọ́n yóò sì ní agbára irin díẹ̀ nínú rẹ̀, bí ó ṣe rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀.

42 Bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ ṣe jẹ́ apákan irin àti apákan amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóò lágbára lápákan tí kò sì ní lágbára lápákan.

43 Gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀, báyìí ni àwọn ènìyàn yóò ṣe dàpọ̀ mọ́ ara wọn ní ti ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n wọn kò ní wà ní ìṣọ̀kan, bí irin kò ṣe dàpọ̀ mọ́ amọ̀.

44 “Ní àsìkò àwọn ọba náà, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba èyí tí kò le è bàjẹ́ kalẹ̀, èyí tí a kò ní fi lé ẹlòmíràn lọ́wọ́. Yóò sì run gbogbo ìjọba, yóò sì mú wọn wá sí òpin, ṣùgbọ́n ìjọba yìí yóò dúró láéláé.”

45 Gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i pé a gé òkúta láti ara òkè, láì ti ọwọ́ ẹnikẹ́ni wá, òkúta èyí tí ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fàdákà àti wúrà sí wẹ́wẹ́.“Ọlọ́run tí ó tóbi ti fi han ọba, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Òtítọ́ ni àlá náà, bẹ́ẹ̀ ni ìtúmọ̀ rẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé.”

46 Nígbà náà, ni Nebukadinésárì ọba dojúbolẹ̀ níwájú u Dáníẹ́lì ó sì fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọn kí ó mu ọrẹ àti òórùn tùràrí fún Dáníẹ́lì

47 Ọba wí fún Dáníẹ́lì pé, “Dájúdájú Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn ọba gbogbo àti olùfihàn àwọn àsírí, nítorí tí ìwọ lè fi àsírí yìí hàn.”

48 Nígbà náà ni ọba gbé Dáníẹ́lì ga, ó sì fún un ní ẹ̀bùn ńlá tí ó pọ̀. Ó sì fi ṣe olórí i gbogbo agbègbè ìjọba Bábílónì àti olórí gbogbo àwọn amòye Bábílónì.

49 Dáníẹ́lì béèrè lọ́wọ́ ọba, ó sì yan Sádírákì, Mésákì, àti Àbẹ́dinígò gẹ́gẹ́ bí alábojútó ìgbéríko Bábílónì ṣùgbọ́n Dáníẹ́lì fún ra rẹ̀ wà ní ààfin ọba.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12