1 Nebukadinésárì ọba,Sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé:Kí Àlàáfíà máa pọ̀ síi fún un yín.Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀!
2 Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ àmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo ti ṣe fún mi hàn.
3 Báwo ni àmì rẹ̀ ti tóbi tó,Báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó!Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni;ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni.
4 Èmi Nebukadinéṣárì wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà.