Dáníẹ́lì 4:11-17 BMY

11 Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí i rẹ̀ sì ń kan ọ̀run; a sì rí i títí dé òpin ayé.

12 Ewé e rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn. Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ká rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ.

13 “Lórí ibùsùn mi, mo rí ìran náà, olùṣọ́ kan dúró ṣíwájú u mi, àní ẹni mímọ́ kan, ó ń bọ̀ wá láti ọ̀run

14 ó kígbe sókè wí pé, ‘Gé igi náà kí o sì gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò; gbọn ewé ẹ rẹ̀ ká, kí o sì fọ́n èṣo rẹ̀ dànù. Jẹ́ kí àwọn ẹranko tí ó wà lábẹ́ ẹ rẹ̀ sá àti àwọn ẹyẹ tí ó wà ní ẹ̀ka rẹ̀ kúrò.

15 Ṣùgbọ́n fi kùkùté àti gbòǹgbò o rẹ̀ tí a fi irin àti idẹ dè ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ àti sí orí i koríko igbó.“ ‘Jẹ́ kí ìrì ọ̀run ṣẹ̀ sí i lára, kí ó sì jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ẹranko igbó láàrin ilẹ̀ ayé.

16 Jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ kí ó yí padà kúrò ní ti ènìyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.

17 “ ‘Olùṣọ́ ni ó gbé ìpinnu náà jáde, àṣẹ sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́, kí gbogbo alààyè le mọ̀ wí pé, Ọ̀gá Ògò ni olórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹnikẹ́ni tí ó wù ú, òun sì ń gbé onírẹ̀lẹ̀ lórí i wọn.’