Dáníẹ́lì 4:19-25 BMY

19 Nígbà náà ni Dáníẹ́lì (ẹni tí à ń pè ní Beliteṣáṣárì) páyà gidigidi fún ìgbà díẹ̀, èrò inú un rẹ̀ sì bà á lẹ́rù. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Beliteṣáṣárì, má ṣe jẹ́ kí àlá náà tàbí ìtumọ̀ rẹ̀ kí ó dẹ́rù bà ọ́.”Beliteṣáṣárì sì dáhùn wí pé, “Olúwa mi, kí àlá yìí jẹ́ ti àwọn ọ̀tá a rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn aṣòdì sí ọ:

20 Igi tí ìwọ rí, tí ó dàgbà, tí ó sì lágbára, tí orí i rẹ̀ sì ń kan ọ̀run, tí ó lẹ́wà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso, tí ó ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn, tí ó ṣe ààbò lórí ẹranko igbó àti èyí tí ẹ̀ka rẹ̀ pèsè àyè fún ẹyẹ ojú ọ̀run.

21 Èyí tí ewé e rẹ̀ lẹ́wà, tí èṣo rẹ̀ si pọ̀, nínú èyí tí oúnjẹ sì wà fún gbogbo ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí àwọn ẹranko ìgbó ń gbé, lórí ẹ̀ka èyí ti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní ibùgbé wọn.

22 Ìwọ ọba ni igi náà, ìwọ ti dàgbà, o sì lágbára, títóbi i rẹ ga ó sì kan ọ̀run, ìjọba rẹ sì gbilẹ̀ títí dé òpin ayé.

23 “Ìwọ ọba, rí ìránṣẹ́ ẹni mímọ́ kan, tí ó ń bọ̀ láti ọ̀run ó sì sọ pé, ‘Gé igi náà kí o sì run ún, ṣùgbọ́n fi kùkùté rẹ tí a dè pẹ̀lú irin àti idẹ sílẹ̀ nínú koríko igbó, nígbà tí gbòǹgbò rẹ̀ sì wà nínú ilẹ̀ kí o sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run ṣẹ̀ sórí i rẹ̀, jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà láàrin ẹranko búburú títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.’

24 “Èyí ni ìtúmọ̀ àlá rẹ ọba àti àṣẹ tí Ọ̀gá Ògo mú wá sórí ọba olúwa mi:

25 A ó lé ọ jáde kúrò láàrin ènìyàn, ìwọ yóò sì máa gbé láàrin ẹranko búburú: ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run yóò sì sẹ̀ sára rẹ. Ìgbà méje yóò sì kọjá lórí ì rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé Ọ̀gá Ògo ń jọba lórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.