1 Ní ọdún àkọ́kọ́ Beliṣáṣárì ọba Bábílónì, Dáníẹ́lì lá àlá kan, ìran náà sì wá sí ọkàn an rẹ̀ bí ó ṣe ṣùn sórí ibùṣùn un rẹ̀, ó sì kọ àlá náà sílẹ̀.
2 Dáníẹ́lì sọ pé, “Nínú ìran mi lóru mo wò ó, mo sì rí afẹ́fẹ́ ọ̀run mẹ́rin tí ó ń ru omi òkun ńlá sókè.
3 Ẹranko ńlá mẹ́rin tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, jáde láti inú òkun náà.
4 “Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́-apá a idì: mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́-apá rẹ̀ naa tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un.