14 Ó sọ fún mi pé, “Yóò gbà tó ẹgbọ̀kànlá lé lọ́gọ́rùn-ún (2,300) alẹ́ àti òwúrọ̀; lẹ́yìn náà ni a ó tún ibi mímọ́ yà sí mímọ́.”
15 Nígbà tí èmi Dáníẹ́lì, ń wo ìran náà, mo sì ń fẹ́ kí ó yé mi, ẹnìkan tí ó sì dúró níwájú ù mi.
16 Mo gbọ́ ohùn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ Úláì, tí ó ń pè pẹ́ “Gébúrẹ́lì, sọ ìtumọ̀ ìran náà fún ọkùnrin yìí.”
17 Bí ó ṣe súnmọ́ ibi tí mo dúró sí, ẹ̀rù bàmí, mo sì dọ̀bálẹ̀. Ó ń sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ́ kí ó yé ọ pé ìran náà ń sọ nípa ìgbà ìkẹyìn ni.”
18 Bí ó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo ti sùn lọ fọnfọn, bí mo ṣe da ojú bolẹ̀. Nígbà náà ni ó fi ọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi.
19 Ó sọ wí pé: “Èmi yóò sọ ohun tí yóò sẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ní ìgbà ìbínú, nítorí ìran náà jẹ mọ́ àkókò ohun tí a yàn nígbà ìkẹyìn.
20 Àgbò oníwo méjì tí o rí, òun ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba Médíánì àti Páṣíà.